India: Ọkurin kan yọ kindinrin iyawo rẹ

Aworan isẹ abẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Obinrin naa ni wọn yọ kindinrin oun lai sọ fun oun

Ọwọ awọn ọlọpa ti tẹ ọkọ obinrin kan to jẹ ọmọ India ati aburo ọkọ rẹ ọkunrin kan lẹyin to sọ fun awọn ọlọpa wipe awọn mejeeji ji kindinrin ohun lati fi rọpo owo ori.

Lọdun 2017, eto ayẹwo ilera meji ọtọọtọ fi idi rẹ mulẹ pe ikan lara awọn kindinrin obinrin naa ti poora.

O fi ẹsun kan ọkọ rẹ wipe gboogbo igba lo maa n beere owo ori lọwọ oun.

Eto owo ori sisan ni India lati ọwọ awọn ẹbi iyawo fun ẹbi ọkọ , ni wọn ti fi ofin de lati 1961.

Nigba ti oun ba awọn oniroyin orileede India sọrọ, obinrin naa, Rita Sarkar ni alubolẹ ni ọkọ oun maa n lu oun fun ọpọlọpọ ọdun nitori owo ori naa.

Iwe iroyin Hindustan Times jabọ wipe obinrin naa ni "ọkọ mi mu mi lọ si ileewosan aladani kan ni Kolkata, nibiti oun ati oṣiṣ'ẹ eleto ilera kan ti sọ fun mi wipe ara mi yoo balẹ̀ lẹyin ti wọn sẹ iṣẹ abẹ lati yọ okuta inu (appendix) mi."

"Ọkọ mi kilọ fun mi pe mi o gbọdọ sọ fun ẹnikẹni nipa iṣẹ abẹ naa."

O ni, lẹyin oṣu diẹ, inira de ba oun, awọn mọlẹbi oun si gbe oun lọ si ọdọ dokita kan. Eto ayẹwo ti wọn ṣe fun fihan pe kindinrin rẹ kan ti di awati. Ayẹwo keji si fi idi rẹ mulẹ.

O sọ fun iwe iroyin Hindustan Times pe "Igba naa ni o to o yemi, idi ti ọkọ mi fi ni ki un pa ẹnu mi mọ lori iṣẹ abẹ naa."

"O ta kindinrin mi nitori wipe agbara mọlẹbi mi o ka owo ori ti oun beere fun."

Iwe iroyin Telegraph ni orileede India ni ọga agba fun ileesẹ ọlọpa, Udayshankar Ghosh sọ wipe: "A n fura wipe ọrọ naa ni bayo-bayo ninu.

"A ṣe akọsilẹ ẹjọ naa labẹ ofin to ni i ṣe pẹlu ṣise paṣi-paarọ ya ara.

"A si ti mu eniyan mẹta fun ẹsun igbiyanju lati sekupani to fi mọ ifiyajẹni."