Ẹmi mokanlẹladorin s'ofo ninu ajalu baalu ilẹ Russia

Wọn ri igeku baalu naa lori papa kan ni guusu ila orun Moscow Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Wọn ri ageku baalu naa lori papa kan ni guusu ila orun Moscow

Gbogbo eeyan mokanlẹladorin to wa ninu baalu Russia kan to jabọ ni ọjọ aiku ni wọn ku.

Ọkọ-ofurufu naa jabọ ni lẹyin igba to leyin igba to gbera kuro ni papa ofurufu Moscow lo si agbegbe Urals.

Baalu ileesẹ ọkọ-ofurufu Saratov Airlines ton lo si igboro Orsk jabo ni abule Argunovo, to to ọgọrin kilomita si guusu ila orun Moscow.

Awọn aworan lati ibiti baalu naa bo si se afihan ageku ọkọ-ofurufu naa lori papa ti o kun fun yinyin.

Ọkan lara awọn osisẹ iranwọ pajawiri so fun ileesẹ iroyin Interfax wipe baalu naa jabọ ni, kosi si aye fun ẹnikẹni lati jade laaye lati inurẹ.

Image copyright Image copyrightFLIGHRADAR24
Àkọlé àwòrán Oju opo ayelujara Flightradar24 se afihan ọ̀na ti baalu naa gba

Ẹni naa s'afikun wipe ọsisẹ baalu mẹfa lo wa ninu ọkọ-ofurufu naa.

O sọ wipe baalu na jabọ lẹgbẹ abule Argunovo.

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Irufẹ baalu to wa ninu aworan yi lo jabọ