Ijamba Italy: Awọn arinrinajo fori sọta ni Macerata

Luca Traini ti wa lagọ ọlọọpa Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Won furasi Luca Traini pe o se eniyan mẹfa lọṣẹ

Jennifer Otioto, ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn sọrọ lati ile iwosan rẹ wipe "Mo ṣẹṣẹ de si orilẹede Italy ni"

Ni owurọ ọjọ kẹta osu keji, Otioto duro ni ibudokọ akero ni ilu Macerata.

Ọkunrin Italy kan ti o jẹ ọmọ ọdun mejidinlọgbọn, Luca Traini, lọ si ọdọ rẹ ni Alfa Romeo o si yin in nibọn.

Otioto, ti o jẹ onidiri ti wa ninu irora ijamba ibọn lọwọlọwọ bayi. O wa ninu ibanujẹ latari isẹlẹ yi pẹlu.

"Iru wahala bayi ko ye mi rara," o sọ.

Luca Traini yinbọn si eniyan marun lọjọ yẹn. Ko si ẹni ti o ku ninu wọn, gbogbo wọn ye.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ami oju ọta ibọn ti apaniyan yi fẹ fi pa awn eniyan

O farahan pe o se afojusun ẹnikẹni ti o dabi pe wọn wa lati ilẹ Afirika.

Kofi Wilson, ti o jẹ ọmọ ogun ọdun lati orilẹ̀ede Ghanan jade l lati lọọ ge irun ori rẹ nigbati o kagbako. O gba ọta ibọn ni aya rẹ.

"A gbọ ti awọn iro ibọn ndun ni akọkọ," Wilson rántí. "Lẹhin awọn iro ibọn akọkọ yi, a ko gbọ nnkan kan mọ", o sọrọ.

Àkọlé àwòrán Kofi Wilson fara gbọta nigbati o lọ ge irun ori rẹ

"Kii ṣe ipinnu mi lati jẹ dudu [eniyan]," o tẹsiwaju. "O jẹ aṣiṣe buburu lati [gbiyanju lati] pa eniyan dudu."

Kofi Wilson ti wa ni Itali fun ọdun mẹta. Ibon yiyan fun un yi ko mu ki o yi okan rẹ pada nipa ọjọ iwaju rẹ. Ko ni ipinnu lati pada si Ghana.

"Emi yoo fẹ lati duro ni Italy, ko da fun igba iyoku aye mi."

Ṣugbọn otitọ ni wipe ọpọlọpọ awọn ọmọ Italy yoo fẹ lati ri pe ki awọn eniyan lọ kuro nilu wọn.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Iwọde ifẹhonuhan ti n waye ni awọn agbegbe kan ni orilẹede Italy lori isele yi

Awọn ọkẹ mẹrin eniyan ngbe ilu yii. Olori Macerata, (Mayor) Romano Carancini sọ wipe ida mẹsan ninu ọgọrun ninu awọn olugbe ilu naa jẹ awọn aṣikiri tabi arinrinajo.