Wọn ṣi aworan Obama ati Michelle

Barack ati Michelle Obama nibi ifilọlẹ aworan wọn Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Inu Aarẹ America tẹlẹri dun si aworan wonyi

Ayẹyẹ ṣiṣi awọn aworan aarẹ America tẹlẹri, Barrack Obama ati iyawo rẹ Michelle Obama ti waye ni Smithsonian's National Portrait Gallery nilu Washington DC l'Amerika.

Aarẹ Amẹrika tẹlẹri sọ pe aworan oun ti Kehinde Wiley, to jẹ ọmọ Nigeria ya jẹ "eyi to dara".

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Barack Obama sọ pe aworan yii dara pupọ

Iyalẹnu nla lo jẹ fun Michelle Obama, iyawo aarẹ nigbati wọn ṣi'ṣọ loju aworan rẹ, eyi ti Amy Sherald, ayaworan miiran to jẹ alawọ dudu ya.

Steven Spielberg ati Tom Hanks wa laaarin awọn alejo nibi ifilọlẹ naa.

"Ko si ẹnikẹni ti mo mọ ninu ẹbi mi ti wọn ya aworan wọn bayi,"Aarẹ Obama sọrọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kehinde Wiley jẹ ayawoyan l'Amerika, sugbọn baba rẹ jẹ ọmọ bibi Nigeria

O se awada pe aworan rẹ jẹ eyi ti o dara julọ ninu awọn aworan ara rẹ ti o ti ri lati igba ewe rẹ nile iwe giga.

Obama gboriyin fun arabinrin Sherald fun bi o ṣe safihan ẹwa iyawo oun ninu aworan rẹ to ya.

Abilekọ Obama ninu ọrọ ti ẹ ni aworan rẹ ti Sherald ya yoo jẹ ohun maleegbagbe ati imoriwu fun awọn obinrin to jẹ alawọ dudu.