Ìyibọ́npaniyan ile-iwe Florida: Eeyan mẹ́tadinlogun ti ku

Awọn ọmọ ile iwe to jade

Oríṣun àwòrán, EVN

Àkọlé àwòrán,

Aworan amohunmọworan s'afihan bi wọn tin ko awọn ọmọ ile iwe jade kuro ninu ewu

Ọmọ ile-iwe metadinlogun ni wọn ku lẹyin igba ti ọmọ ọdun mokandinlogun kan yinbọn fun awọn eeyan ni ọgba ile-iwe giga kan ni Parkland, to wa ni ipinlẹ Florida l'orilẹ̀ede America.

Awọn ọlọpa si tun sọ wipẹ orukọ afurasi naa ni Nikolas Cruz, ọmọ ọdun mọkandinlogun, to jẹ ọmọ ile-iwe ti ile ẹkọ̀ naa le kurọ.

Ni asikọ ti ọdọmọkunrin naa yibọn l'ọwọ, wọn fi tipa mu awọn akẹko f'ori pamọ ti awọn ọlọpa si ya bo ile-iwe naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wọn ko awọn eeyan jade lẹyin ikọlu ibọn naa

Ikọlu yii jẹ ọkan lara iyibọn paniyan ni ile-iwe to buru ju lati igba ti wọn ti paa eniyan mẹridinlọgbọn ni ile-iwe Connecticut kan ni ọ̀dun 2012.

Ọgba ọlọpa ijọba ibilẹ Broward, Scott Israel, sọ̀ fun awọn akọroyin wipe ọgbẹni Cruz pa eeyan mẹta ko to ile-ile iwe naa o si pa eeyan mejila ninu rẹ

Eniyan meji pada ku lẹyin igba ti wọn gbe wọn lo si ilẹ iwosan.

Dokita Evan Boyar ti ile ajọ awọn ile iwe Broward Health sọ fun awọn akọroyin l'ọjọru wipe wọn ti gbe awọn eeyan mẹtadinlogun lo si awọn ile iwosan l'agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán,

Tidunnu ati ayọ l'awọn akẹkọ fi pade awọn obi wọn lẹyin isẹlẹ naa

O s'afikun wipe ọgbẹni Cruz wa ninu awọn ti tọju ati wipe wọn ti nawọ rẹ si awọn ọlọpa. Eeyan mẹta si wa ninu isesi to l'ewu lasiko ti eeyan mẹta miran wa ninu isesi to balẹ.

Wọn sin gbiyanju ati da awọn ẹniti ajalu naa ba l'ọwọ. Ọgba ọlọpa Israel sọ wipe olukọni ere boolu kan wa ninu awọn ti wọn ku, sugbọn wọn ko ti gbe orukọ kankan jade.