Pakistan dajọ iku mẹrin f'ẹni fi'pa b'ọmọ ọdun mẹfa lọ to fi ku

Wọn pa Zainab Ansari, ọmọ ọ̀dun mẹfa ni Pakistan Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ifipa ba Zainab lọ pọ ati siseku pa ba awọn eeyan lọkan jẹ ni orilẹede Pakistan

Ile ẹjọ kan ni orilẹede Pakistan ti dajọ iku mẹrin ọtọtọ fun ọmọkunrin Imran Ali to f'ipa ba ọmọodun mẹfa lọ to si se iku pa pẹlu. Eyi tumọ si pe ti wọn baa paa lakọkọ ti ko ba ku, wọn yoo tun paa lẹẹkeji titi di ẹlẹẹkẹrin ti yoo fi ku.

Wọn ri oku Zainab Ansari l'ori akitan ni igboro Kasur to wa ni guusu Lahore ni ọjọ kẹsan osu kinni ọdun yii.

Iṣekupa ọmọbirin naa s'ọkunfa ifẹhonu-han kakiri orilẹede naa pẹlu rogbodiyan lori esun aimọse ọlọpa.

Baba ọmọbirin naa lo si ile ẹjọ lati gbọ idajọ naa l'abẹ aabo to peye.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Wọn ti fi ẹsun sise asemase si awọn ọmọbirin miran kan Ali

Awọn ọlọpa ati ọlọtu ipinlẹ f'ẹsun kan apaniyan naa lori ikọlu ati ipaniyan to sẹlẹ si awọn ọmọbirin l'agbegbe naan.

Ogunlọgọ eeyan lo se ẹlẹri ijọba lori ẹjọ Ali nibi ti ẹri ti wọn ti ẹri to peye han.