Agbanipa kan ti sọ wipe ọga NURTW lo ran oun nisẹ

Aworan Rafiu Akanni Ọlohunwa Image copyright Rafiu Akanni Ọlohunwa/Facebook

Ọwọ ọlọpa ti tẹ gbajumọ ọmọ ẹgbẹ awakọ orilẹede Naijiria (NURTW), Rafiu Akanni Ọlohunwa ati afurasi kan, Adeola Willams ti inagijẹ rẹn njẹ Ade Lawyer.

Ikọ ọlọpa pataki ti olori ọlọpa orilẹede Naijiria yan fun igb'ogun ti pipaniyan ati jijiniyan gbe ( Inteligence Response Team) si mu Ade Lawyer to jẹ ọmọ ẹgbẹ NURTW lori ẹsun ipaniyan.

Agbẹnusọ fun ile isẹ ọlọpa Naijiria, Jimoh Moshood, fidi iroyin naa mulẹ fun BBC.

Ọgbẹni Moshood sọ wipe awọn afurasi naa wọn yoo f'oju ba ile ẹjọ.

Awọn ọlọpọ naa sọ wipe Ade Lawyer jẹwọ pe oun lo pa Rasaq Bello, ti gbogbo eeyan mọ si Hamburger.

Wọn sọ wipe ni igboro Akurẹ, ni ipinlẹ Ondo, ni wọn ti mu afurasi naa.

Awọn ọlọpa ni orukọ Ade Lawyer ti wa ninu awọn ti wọn wa lati nkan bi dun marun s'ẹyin.

Awọn ọlọpa fura si Ọlohunwa wipe owun lo gbe ise fun Ade Lawyer lati pa ọga NURTW ni Lagos Island, Azeez Lawal (ti wọn n pe ni Kunle Poly).

Wọn sọ wipe Ade Lawyer jẹwọ fun wọn wipe oun gba 500,000 naira l'ọwọ Olohunwa pẹlu adehun wipe yoo gba miliọnu kan naira lẹyin igba to ba pari ise naa.

Sugbọn kaka ki ibọn Ade Lawyer pa Kunle Poly, ọmọ ẹyin rẹ lo pa.

Lẹyin igba ti wọn mu, Ade Lawyer sọ wipe Olọhunwa kọ lati fun ni miliọnu kan naira to ku nitori wipe Kunle Poly ko ku.