Naijiria ti da awọn afurasi Boko Haram 475 silẹ

Ọmọogun orilẹede Naijiria nipinlẹ Borno Image copyright AFP

Ile ẹjọ Naijiria kan ti da awọn afurasi ẹgbẹ Boko Haram orinlenirinwo silẹ nitori ati se itọju to peye fun wọn.

Ile ẹjọ naa si fo wọn mọn kuro nibi gbogbo ẹsun idunkoko moni ti wọn fi kan wọn nigba igbẹjọ wọn.

Wọn mun awọn olujẹẹjọ naa lasiko otọtọ l'awọn agbegbe to yatọ sirawọn lasiko idunkoko Boko Haram.

Awọn kan lara awọn ti wọn da silẹ naa ti wa latimọle lati ọdun 2010.

Ile ẹjọ da awọn afurasi naa ti wọn le ni ogorun mẹrin silẹ nitori aisi ẹri to muna d'oko to fi han wipe ọmọ Boko Haram ni wọn.

Minista Naijiria fun eto idajọ sọ wipe wọn yoo se itọju to peye fun wọn ki wọn to nawọ wọn fun awọn ẹbi wọn.

Itusilẹ wọn jẹ igbesẹ kan ninu igbẹjọ awọn afurasi Boko Haram to n lọ l'ọwọ ni ileese ologun kan to wa ni ilu Kainji, ni ipilẹ Niger.