Abdul Ganiyu: Didabẹ f'ọmọkunrin lodi s'ofin ẹsin

Okunrin kan n da abẹ fun omodekunrin kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aba madabẹmọ lodi si eto aṣa ati iṣe Yoruba ati ẹsin musulumi - Alfa Ganiyu

Ọpọlọpọ awuyewuye ti n waye lori aba kan lorilẹede Iceland to sọọ di ẹsẹ fun ẹnikẹni lati da'bẹ fun awọn ọmọ ọkunrin.

Ẹgbẹ oṣelu kan mu aba yi wa wipe abẹ dida fun awọn ọmọkunrin lodi si ẹtọ awọn ọmọ bẹẹ, ati wipe o yẹ ki obi wọn duro ki wọn dagba lati se ipinnu funra wọn lori abẹ dida.

Amọsa, asiwaju ẹsin musulumi kan ni orilẹede Iceland ti koro oju si igbesẹ yii.

Oju ti asiwaju ẹsin naa, Ahmad Seddeeq, fi wo ọrọ ọhun ni wipe o tako ẹtọ ati se ẹsin ẹni tabi awọn ilana to rọ mọọ bo ti se wuni.

Ahmad Seddeeq to jẹ imaamu ni ibudo asa ẹsin Islam to wa ni orilẹede Iceland ṣalaye fun BBC wipe ọkan gboogi lara ilana ẹsin Islam ni asa dida abẹ fun ọmọ ọkunrin jẹ ati wi pe yoo jẹ ohun to buru jai lati wa lẹ ontẹ iwa ọdaran mọ asa naa lara.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Labẹ ofin ti wọn n gbero yii, ijiya ọdun mẹfa n bẹ ni ikalẹ lorilẹede Iceland fun ẹnikẹni to ba da abẹ fun ọmọkunrin

Abadofin kan to wa niwaju ileegbimọ asofin orilẹede Iceland lọwọlọwọ bayii lo n fonrere rẹ wi pe ki wọn maa fi ijiya ti o to ọdun mẹfa jẹ ẹnikẹni ti aje rẹ ba si mọ lori wi pe o n da abẹ fun ọmọde yala nitori ọrọ ẹsin tabi ọrọ asa.

Awọn to n se agbatẹru ofin yii fi ọrọ ọhun se akawe pẹlu igbesẹ dida'bẹ fun awọn ọmọbinrin, eyi ti wọn si ni ko si bameji ju wipe igbesẹ naa n tẹ ẹtọ awọn ọmọ ọkunrin loju mọlẹ.

Bakannaa lawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ gbogbo to rọ mọ ẹsin Juu pẹlu ti koro oju si igbesẹ yii.

Adari ẹsin kan nipinlẹ Eko, Alfa Abdul Ganiyi sọ fun BBC Yoruba pe aba yi lodi si eto aṣa ati iṣe Yoruba ati ẹsin musulumi. O ṣalaye wipe gbogbo ọna ti ko ba jọ mọ ilana ẹsin ati awọn ohun adayeba ko gbọdọ jọba lawujọ.

Alfa Ganiyu bu ẹnu atẹ lu aba naa, o ran awọn obi leti ipa wọn lati ṣe ojuṣe wọn ni kete ti wọn ba tii bi awọn ọmọ ọkunrin.

Related Topics