Billy Graham dagbere f‘aye

Billy Graham Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kaakiri awọn orilẹede agbaye ni Billy Graham ti waasu ihinrere de

Gbajugbaja oniwaasu kan lati orilẹede Amerika, tii se ọkan lara awọn oniwaasu to gbajumọ ju ni saa onka ọdun 1900, Billy Graham, ti papoda lẹni ọdunmọkandinlọgọrun.

Graham jẹ ọkan lara awọn ti wọn gbajumọ nidi gbigbe ẹsin kristẹni ga, to sin maa nse iwaasu fawọn eeyan pupo l'agbaye, lati ọdun 1954.

Iroyin naa ni Graham se iwaasu fawọn eeyan ti wọn le ni miliọnu lọna okoolerugba o din mẹwa laarin ọgọta ọdun.

Graham ko kọkọ nigbagbọ ninu bawọn alawọ dudu lorilẹede Amẹrika se nja fẹtọ ọmọniyan, amọ nigba to ya, o pada di alatileyin fun eto ajafẹtọẹni naa lati ọdun 1950.

O di onigbagbọ to mu ẹsin lọkunkundun nigba to wa lọmọ ọdun mẹrindinlogun lẹyin to gbo ọrọ oniwaasu kan, toun gangan si di oniwaasu lọdun 1939.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí