Ibo 2019: Ọọni ni ibo tita fun oloselu ko tọ

Ọọni Ifẹ Ọba Adeyẹyẹ Ogunwusi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ibo tita fawọn oloselu ko ni jẹki wọn jiyin isẹ iriju wọn

Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi Ọjaja keji, ti kesi awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti to dibọ lati ma se ta ibọ wọn fun awọn oloselu.

Oriade naa to parọwa yii l'Ọjọbọ tun sọ wipe isoro pọ fun orilẹede Naijiria.

O salaye pe Naijiria nilo ati yi eto iselu rẹ pada pẹlu afikun pe asa tita ibo fawọn oloselu ko ni fun awọn eeyan l'anfani ati bi awọn asaaju leere nipa awọn nkan to se pataki fun ilọsiwaju orilẹede.

Ọọni parowa yi nibi eto ironilagbara fawọn obinrin nilu Ilẹ Ifẹ ati awọn ilu miran lẹkun iwọ-orun guusu Naijiria.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ọọni ni o yẹ ka yi ilana oselu wa pada ni Naijiria

O sọ wipe " Tawọn oloselu ba wa polongo ibọ, ẹ ma ta ibọ yin fun wọn. Ẹ sọ fun wọn wipe ki wọn lọ fi ọwọ naa se itọrẹ aanu fun awọn ẹgbẹ alaanu.

"Iransẹ ilu ni awọn asaaju jẹ. Awa la dibọ fun wọn. Asiko to lati bi wọn lawọn ibeere kan. Ẹ je ka yi eto iselu orilẹede yii pada."