Lẹta iwasẹ ti oludasilẹ ileesẹ Apple kọ l'ọdun 1973 ti wa fun tita

Aworan Steve Jobs ati iwe-iwasẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty/RR Auction

Àkọlé àwòrán,

Lẹta iwasẹ ọdun 1973 naa s'afihan erongba Steve Jobs

Wọn reti wipe wọn yoo ta iwe-iwasẹ ọdun 1973 kan ti oludasilẹ Apple, Steve Jobs, kọ ni ẹgbẹrun lọna adọta dọla ($50,000) ti se miliọnu mejidinlogun (18) naira.

Iwe naa ti Jobs kọ nigba to ku ọdun mẹta ti yoo fi da ileesẹ to sọ di ọkan lara awọn to lowo julọ lagbaye kun fun awọn asisẹ kik'ọrọ-silẹ.

Iwe ọhun to jẹ alabala kan s'afihan erongba Jobs nipa imọ-ẹrọ saaju ko to wọ gbagede ise naa.

Ninu awọn nkan to darukọ pe oun le se ni "imọ-ẹrọ itanna tabi imọ-ẹrọ ọna", o si sọ wipe oun nimọ bi kọmputa tin sisẹ.

Ko si aridaju nkan to kọ iwe-iwasẹ naa fun tabi wipe boya Jobs yege nibi nkan to wa nigba naa.

O kọ orukọ rẹ gẹgẹ bi "Steven jobs" o si pe ibugbe rẹ ni "reed college", ile iwe to lọ fun 'gbadiẹ ni Portland, Oregon ko to fi iwe-kika silẹ.

Lori fọmu naa Jobs ni lootọ oun ni iwe asẹ iwakọ, sugbọn nigba ti wọn bi lere wipe se ọwọ rẹ to ọkọ kan, o dahun wipe "o seese, sugbọn ole ma jẹ bẹ."

Lẹgbẹ "Fonu" ẹni to da ẹrọibanisọrọ iPhone silẹ kọ "kosi nkan kan."

Jobs ba aisan jẹjẹrẹ lọ l'ọmọodun mẹrindinladọta (56) ni ọdun 2011.