Bollywood padanu Sridevi

Aworan Sridevi nibikan ni Dubai

Oríṣun àwòrán, Mr Jayakumar

Àkọlé àwòrán,

Sridevi ya awọran yii to jẹ ọkan lara awọn aworan to ya kain nibi ayẹyẹ kan to lọ ni Dubai

Gbajugbaja osere fiimu Bollywood Sridevi Kapoor ti ba arun ọkan lọ, gẹgẹ bi awọn ẹbi rẹ ti sọ.

O ku lẹni ọdun mẹrinleladọta.

Osere naa, ti awọn eeyan mọ si Sridevi, lọ si ọdọ awọn ẹbi rẹ ni Dubai nitori igbeyawo ọkan lara wọn.

Laarin ọdun to le ni adọta, osere naa kopa ninu fiimu to le ni 150.

Ninu awọn fiimu naa ni Mr India, Chandni, ChaalBaaz ati Sadma.

O jẹ ọkan lara awọn oserebirin India diẹ ti wọn se awọn fiimu to milu titi lai ri atilẹyin akikanju ọkunrin kankan.

Latigba to ti di ọmọ ọdun mẹrin loti bẹrẹ sini kopa ninu fiimu ni ede Tamil, Telugu, Malayalam, Kannada ati Hindi .

Ero pejọ si waju ile awọn Sridevi ni igboro Mumbai nigba ti iroyin iku rẹ jade. Awọn ọsere Bollywood ati oloselu bọkanjẹ lori iku rẹ

Olootu orilẹede India Narendra Modi sọ lori akanni faran Twitter rẹ wipe iku osere na "ba oun lọkan jẹ ", nigbati Aarẹ India President Ram Nath Kovind sọ wipe iku rẹ ti ko awọn ololufẹ rẹ ti wọn le ni miliọnu sinu ọfọ.

Alakoso-igboro London, Sadiq Khan, gboriyin fun irawọ osere naa lori akanni opo Twitter rẹ wipe: "Inu mi dun lati pade Sri Devi to jẹ jankan ninu Bollywood nigba ti mo lọ si India lẹnu ijọ mẹta yii.

"Ọkan mi bajẹ lati gbọ iro iku oserebirin to mọ ere se to baun."