"Next Level" Ààrẹ Buhari àti APC ló gbòde báyìí

NEXT LEVEL

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Àkọlé àwòrán,

Reno Omokri ní ọjọgbọ́n kan ní Winthrop University ló ni àsíà 'Next Level' tí Buhari lò fún ìpolongo sáà kejí rẹ̀.

Ọkan gboogi lara awọn alatako ẹgbẹ oselu APC ati Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi lede pe ẹgbẹ oselu to wa ni ijọba ji asia "Next Level" ti wọn n lo fun ipolongo idibo sipo aarẹ lọdun 2019.

Reno Omokri fi lede lori ẹrọ ayelujara Twitter rẹ pe igbakeji ọjọgbon kan ti orukọ rẹ n jẹ Kelly Costner lo se ifilọẹ "Next Level" lati jẹ ki awọn ọmọ ile iwe giga Winthrop University kọ ẹkọ Ede Gẹẹsi fun imugbooro ibasepọ laarin idile.

Omokri wa kesi awọn ọdọ lorilẹ-ede Naijiria lati mọ daju wi pe awọn kọ́ ni ọ̀le, sugbọn Aarẹ Buhari ati awọn ẹgbẹ ipolongo rẹ ni ọ̀le.

Àkọlé fídíò,

Car Race: Elizade àti Akeredolu kópa nínú ìdíje eré sísá ni Ondo

Festus Keyamọ fèsì lórí ẹ̀sùn naa pe:

Nigba ti BBC kàn si Festus Keyamo to jẹ adari ipolongo Buhari fun idibo 2019, ọ̀tọ̀ ni ọmọ ṣori lọdọ rẹ̀.

Adari ipolongo Aarẹ Buhari, Festus Keyamo, fesi pe kii se asia ẹgbẹ APC ni o wa lori ẹrọ ayelujara, ati wi pe awọn alatako lo n tiraka lati ba isẹ awọn jẹ.

O ni irọ ni pẹpẹ awọn alatako n pa, àjà lo lẹrù ni ọrọ ipolongo Buhari fún idibo 2019.

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Àkọlé àwòrán,

Lọjọ Aiku ni Aarẹ Buhari ṣe ifilọlẹ iwe eto ijọba ohun ti o pe akori rẹ ni Next Level.

Keyamo sọ pe asia naa yatọ patapata, ati pe ila asia ti wọn lo si oke, amọ ti eleyii ti wọn ri naa wa si isalẹ.

2019 Election: Naijiria ní àlùmọ́ọ́nì, owó láti mú 'Next Level' Buhari sẹ

Ero awọn eniyan se ọtọọtọ lori iwe ipolongo ti Aarẹ Buhari gbe jade saaju idibo sipo aarẹ lorilẹ-ede Naijiria ni idibo gbogboogbo ti 2019.

Asofin tẹlẹri, Honourable Mojeed Olaiya sọ wi pe orilẹ-ede Naijiria ni ohun gbogbo bi alumọni ati owo ni akunwọsile lati se atunse ile iwe ẹgbẹwa lọdọọdun.

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ Muhammadu Buhari nínú ìwé ìpolongo rẹ̀ ní òhun yóò se àtúnsẹ ilé ìwé ẹgbẹ̀wá lọ́dọọdún.

Olaiya ni Aarẹ Buhari ko ni gba jẹgudujẹra laaye, eleyii ti oun sọ pe o fa ifasẹhin fun orilẹ-ede Naijiria lati bi ọdun mẹrindinlogun sẹyin, ti Aarẹ Buhari n gbiyanju lati wa ọna abayọ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

World Toilet Day: Aráàlú ní woléwolé yẹ kó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ojúlé dé ojúlé

Amọ, ọkan gboogi lara awọn igbimọ agba ni ilẹ Yoruba, Akin Oke, lero ti rẹ ni ilẹ Yoruba o setan lati gbẹkele ipolongo to nii se pẹlu atunse ile iwe ẹgbẹwa lọdọọdun.

Oke sọ wi pe ohun to jẹ Yoruba logun ju ni ki atuntọ o waye lorilẹede Naijiria, ki ipinlẹ kọọkan ko fun ra rẹ seto bi ipinlẹ awọn yoo se tẹsiwaju.

O fikun wi pe ileri ati se atunsẹ ile iwe ko jọ awọn Yoruba loju nitori lati ọgbọn ọdun ni awọn ti n gbo ileri to jọ bẹẹ.

Bakan naa ni ero awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ikansiraẹni Facebook se ọtọọtọ lasiko ti wọn n fesi si iwe ipolongo tuntun naa.

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Àkọlé àwòrán,

Lara awọn ileri Aarẹ Muhammadu Buhari ni lati ya ida márùndínlógójì ninu ida ọgọ́rùn ún ipo ijọba silẹ fawọn obinrin

Lara awọn ileri Aarẹ Muhammadu Buhari ni lati ya ida márùndínlógójì ninu ida ọgọ́rùn ún ipo ijọba silẹ fawọn obinrin.

Buhari gbé 'Next Level' jáde bíi ìwé ìpolongo ìbò rẹ̀

Aarẹ Buhari ti sẹ ifilọlẹ eto isejọba rẹ tuntun labẹ eto ipolongo idibo Aarẹ 2019

Lọjọ Aiku ni Aarẹ Buhari ṣe ifilọlẹ iwe eto ijọba ohun ti o pe akori rẹ ni Next Level.

Ile ijọba ni ilu Abuja ni ayẹyẹ ifilọlẹ iwe alabala mẹrinla naa ti waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu iwe naa, o se alakalẹ awọn eto to fẹ ṣe labẹ isọri bi mejila ti a si ri ninu wọn:

  • Ipese iṣẹ,
  • Ipese awọn nnkan amayederun,
  • Mimu agbega ba pipese ina ọba,
  • Iranwọ owo,
  • Ile ifowopamọ ti yoo ma pese owo fun awọn oniṣẹ ọwọ,
  • Eto ilera ati mimu alẹkun ba iyẹ awọn ti o n kopa ninu isejọba.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Ọrọ aabọ tabi kikoju awọn agbesunmọmi Boko Haram ati kikoju awọn onijẹgudujẹra ti o jẹ opo pataki ipolongo Aarẹ Buhari lọdun 2015 papọ si abẹ isọri kan ṣoṣo.

Bakanna ninu iwe eto isejọba naa Aarẹ Buhari ni awọn yoo pari afara 2nd Niger, ọna ọkọ ọju irin to lọ lati Eko si Ibadan titi de Kano,ti Eko si Calabar ati awọn miran.

Buhari gẹgẹ bi ohun to ko si inu iwe naa ni ijọba ohun yoo ya gba awọn ọdọ sinu ajọ alasẹ ijọba ati wi pe awọn yoo ya ida márùndínlógójì ninu ida ọgọ́rùn ún ipo ijọba kalẹ fun awọn obinrin.

Oríṣun àwòrán, APC Nigeria

Saaju nii ajọ to n se kokari eto idibo ni Naijiria, Inec, ti kede pe akoko ti to fawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oselu lati bọ sita wa seto ipolongo ibo wọn fawọn ara ilu,awọn oludije ipo Aarẹ ko fẹ fi asiko ṣofo rara.

Ninu awọn to ṣe ọrọ yi ni aaya bẹ silẹ o bẹ sare ni Oby Ezekwesili to jẹ oludije fun ẹgbẹ oselu ACPN.

Loju opo Twitter rẹ lọjọ Aiku, Ezekwwesili fi ikede sita wi pe isin idupe nile ijọsin lohun fẹ fi bẹrẹ ipolongo.

Aarẹ Muhammadu Buhari naa ṣe ifilọlẹ ipolongo rẹ nile ijọba labuja lọjọ aiku pẹlu akori ti o pe ni 'Next Level'

Saaju ifilọlẹ yi ni awọn amugbalẹgbẹ rẹ ti n fi orisirisi ipolongo sita loju opo Twitter sugbọn nigba ti yoo fi to ọwọ irọlẹ ni Bashir Ahmad oluranlowo fun Buhari lori ọrọ iroyin lori ayelujara fi aworan ipolongo yi sita.

Atiku Abubakar to jẹ oludije labẹ asia ẹgbẹ PDP ni oun ṣi n mu ẹyẹ bọ lapo.

Loju opo Twitter rẹ lọjọ Aiku,o ni oun yoo ṣe agbekalẹ ilana iṣejọba ohun ni ọjọ aje ti o si rọ awọn alatilẹyin rẹ lati pade oun lori ẹrọ ayelujara fun ẹkunrẹrẹ.

Bi a ko ba gbagbe, Inec ti saaju rọ awọn oludije ati awọn alatilẹyin wọn pe ki wọn ma ṣe pede abuku sira wọn lasiko ipolongo naa.

Inec ni niwọn igba to jẹ pe ibi taa ba pe ni ori, ẹnikan kii fi ibẹ tẹlẹ, idi ree ti eto ipolongo ibo aarẹ ati tawọn asofin yoo fi side eto ipolongo ibo naa, eyiti o ti gberasọ lọjọ Aiku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìfipábánilòpọ̀: Abiamọ bú sẹ́kún nígbà tí ọkùnrin kan fi tipá bá ọmọ méjì lòpọ̀

Atẹjade kan ti Oludari feto idanilẹkọ ati itaniji fawọn araalu labẹ ajọ Inec, Oluwọle Osaze-Uzzi fisita lo sisọ loju ọrọ.

Osaze Uzzi wa rọ awọn oludije ti ọrọ naa kan, lati gunle ipolongo ibo wọn jake jado orilẹede Naijiria, eyi to wa nibamu pẹlu atẹ ilana eto idibo gbogbo-gboo ọdun 2019.

Bakan naa lo kede pe ọjọ Kinni, osu Kejila ni eto ipolongo ibo fawọn oludije sipo gomina ati ile asofin lawọn ipinlẹ yoo bẹrẹ.

Inec wa rọ awọn oloselu to n kopa ninu eto idibo 2019, lati seto ipolongo ibo wọn ni pẹlẹ-putu, ki wọn si yago fun iwa jagidijagan ni gbogbo ọna, tabi awọn ọrọ alufansa.

Inec yoo bẹrẹ iwadi lori oludibo Kano

Igbimọ ti ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, Inec gbe kalẹ fun ayẹwo awọn eeyan bii miliọnu marun to fi orukọ silẹ gẹgẹbi oludibo ni ipinlẹ Kano yoo bẹrẹ isẹ ni ọjọ Aje.

Ọgaagba kan lajọ INEC, Abubakar Nahuche ni yoo lewaju igbimọ ẹlẹni mẹjọ naa.

Alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Kano, Siec, Ọjọgbọn Garba Sheka ni lọjọ Aje ti igbimọ ba n gunlẹ si ipinlẹ Kano ni wọn yoo de ọdọ oun.

Ọjọgbọn Garba Sheka ni 'Ti igbimọ baa de wọn yoo yọju si ọfiisi mi nibiti a o ti gbe iwe orukọ awọn oludibo le wọn lọwọ. Iwe orukọ ori ẹrọ ayarabiasa ni wọn gbe fun wa, oun naa ni awa pẹlu yoo gbe le wọn lọwọ pada. Bakanaa ni a maa gbe iwe orukọ ti a tẹ jade le wọn lọwọ pẹlu.

Wọn maa yẹẹ wo lati yọ orukọ awọn ọmọde to ba fi orukọ silẹ ninu iwe naa."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Laipẹ yii ni iroyin kan kaakiri orilẹede Naijiria wipe awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko to ọdun mejidinlogun fi orukọ silẹ lati dibo ni ipinlẹ Kano

Amọsa o, alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Kano naa si n fi ọwọ sọya wipe ko si ọmọde kankan to dibo ninu eto idibo si ijọba ibilẹ to waye ni ipinlẹ naa laipẹ yii.

O ni awọn alatako lo n se agbatẹru iroyin pe awọn ọmọde n dibo ni ipinlẹ naa.

Ni ọjọ Ẹti ni alaga ajọ Inec lorilẹede Naijiria gbe igbimọ kalẹ lati se agbeyẹwo ẹsun ti wọn fi kan ajọ naa laipẹ yii wipe o n gba awọn majesin laaye lati fi orukọ silẹ dibo ni ipinlẹ Kano.

Lasiko to fi n se ifilọlẹ igbimọ naa, alaga apapọ ajọ Inec, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ni ko si ohun to kan igbimọ naa pẹlu sise iwadi abajade idibo sijọba ibilẹ to waye ni ipinlẹ Kano nitori ajọ Inec ko lagbara lori rẹ labẹ ofin orilẹede Naijiria.

Kini awọn ohun ti igbimọ Inec yoo mojuto?

Ohun mẹrin ti igbimọ naa yoo bẹrẹ sise lati ọjọ Aje lọ ni:

  • Iwadi boya iwe idibo ti ajọ eleto idibo ipinlẹ Kano beere fun lọwọ ajọ Inec lo fi se idibo sijọba ibilẹ to kọja.
  • Iewadi iroyin to lọ kaakiri wi pe awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko to ọdun mejidinlogun dibo pẹlu iwe idibo naa.
  • Ijiroro pẹlu awọn alẹnulọrọ lori iwe orukọ awọn oludibo naa.
  • Gbigbe aba ati imọran kalẹ eleyii to nii se pẹlu isẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ.

Awọn ọmọ igbimọ naa ni Arabirin May Agbamuche-Mbu, Amofin Mike Igini, Amofin Kassim G. Geidam, Yakubu M. Duku, Arabinrin Rukayat Bunmi Bello, Ọgbẹni Paul Omokore ati Jude Chikezie Okwuonu.

Laipẹ yii ni iroyin kan kaakiri orilẹede Naijiria wipe awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko to ọdun mejidinlogun fi orukọ silẹ lati dibo ni ipinlẹ Kano, eleyi ti ọpọlọpọ eniyan fi oju laifi wo.