Yobe: Awọn to ko ọmọogun kuro gbọdọ jiya

Yobe: Awọn to ko ọmọogun kuro gbọdọ jiya

Dokita Kunle Ọlajide ti kesi ijọba apapọ lati fiya jẹ awọn to ko ọmọogun kuro ni Dapchi.

Ọlajide ni ohun to bani ninujẹ ni pe ina eesi Boko Haram tun jo wa lẹẹmeji, nitori bi wọn se ji awọn akẹkọbinrin Chibok lọ naa ree.

O wa gba ijọba nimọran pe ọga ologun to pasẹ pe kawọn ologun ko aasa wọn kuro ni Dapchi lakoko ti Boko Haram fẹ kọlu ilu naa, lo yẹ ko foju wina ofin.

Ọlajide ko sai tun pe fun atunto orilẹede yii, ki alaafia lee jọba pada.