Yobe: Awọn to ko ọmọogun kuro gbọdọ jiya - YCE

Awọn akẹkọbinrin lapa ariwa Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn akẹkọbinrin to to aadọfa ni Boko Haram ji gbe lọ nilu Dapchi nipinlẹ Yobe

Akọwe apapọ fun ẹgbẹ agbaagba Yoruba (YCE), Dokita Kunle Ọlajide ti fi aidunnu rẹ han si bi ikọ adunkoko mọni Boko Haram se tun ji awọn akẹkọbinrin bii aadọfa gbe lọ nilu Dapchi, nipinlẹ Yobe.

Ọlajide woye bẹẹ nigba to nba ikọ iroyin BBC sọrọ.

O ni o jẹ ohun to bani ninujẹ wipe ikọ Boko Haram tun ri igbin Naijiria gbe pẹlu bo se tun ji awọn akẹkọbinrin gbe nilu Dapchi gẹgẹ bo ti se nilu Chibok.

Akọwe apapọ fun ẹgbẹ agbaagba Yoruba naa wa kesi ijọba apapọ pe ọga ologun to pasẹ pe kawọn ologun kuro nilu naa, ti Boko Haram fi ri aaye ko awọn akẹkọbinrin naa lọ, lo gbọdọ finmu kata ofin.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọ tawọn ologun kuro ni Dapchi lawọn Boko Haram ko akẹkọbinrin lọ

Awọn ọdẹ ibilẹ Yoruba lee rẹyin Boko Haram

Bakanaa lo rọ ijọba apapọ lati se awari awọn akẹkọ Dapchi gẹgẹ bo se gba idande awọn akẹkọ Chibok kan, ki wọn lee darapọ mọ awọn obi wọn laipẹ.

Ọlajide tun woye pe awọn ọdẹ ibilẹ nilẹ Yoruba kaato lati koju ikọ Boko Haram amọ ko ni daa to, ka ko wọn lọ sapa ariwa ilẹ yi ni.

O fikun pe o se ni laanu pe awọn ọdẹ ibilẹ ati awọn araalu kan lawọn agbegbe ti Boko Haram ti nsoro bii agbọn, tun ngba abọde fun orilẹede yi, ti wọn si nse atilẹyin fawọn adunkoko mọni.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn akẹkọbinrin Chibok la nwa, ki Boko Haram tun to gbe akẹkọbinrin ni Dapchi

Ẹ gbọ Dokita Kunle Ọlajide siwaju sii:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYobe: Awọn to ko ọmọogun kuro gbọdọ jiya

Latinu ẹya kọọkan ni Naijiria lo yẹ ki olori ileesẹ ologun ti wa

Ọlajide ko sai wa tun tẹnumọ pe eto atunto orilẹede Naijiria nikan ni o lee mu ki alaafia jọba pada nilẹ Naijiria, ki idagbasoke to yẹ tun lee ba ilẹ yii.

Akọwe apapọ fẹgbẹ agbaagba ilẹ Yoruba tun gba ijọba apapọ nimọran lati maa yan olori ikọ ọmọogun kọọkan latinu gbogbo ẹya to wa lorilẹede yii, kii se latinu ẹya kansoso.