Aarẹ Trump ni asiko to lati koju ilokulo ibọn l'Amẹrika

Aare Trump Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O dabi wi pe Trump setan lati koju ẹgbẹ to'n ja fun lilo ibọn lamerika

Aarẹ Trump ilẹ Amẹrika Donald Trump sọ wipe asiko ti to ki ile aṣofin fọwọ si ẹkunrẹrẹ ofin ti yoo dẹkun ilokulo ibọn lawujọ.

O lede ọrọ naa nigba to'n ba agbarijọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ Democrat ati Republican sọrọ ninu ipade kan ti wọn ṣe afihan rẹ lori ẹrọ amohunmaworan.

Aarẹ Trump ni ki wọn tunbọ mu itẹsiwaju ba ayẹwo finifini ki wọn to o ta ibọn, ki wọn si sun ọjọ ori ti eeyan le ra ibon lati ọdun mejidinlogun si ọdun mọkanlelogun.

O sọ fun awọn aṣofin naa lati maṣe bẹru kikoju ẹgbẹ to'n ja fun lilo ibọn lamerika (NRA).

O sọ pe "Wọn le ni agbara lori yin, ṣugbọn wọn ko lagbara lori mi."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Trump sọ fun awọn aṣofin lati maṣe bẹru ẹgbẹ NRA

Nigba ti o'n du ipo aarẹ lodun 2016, ẹgbẹ NRA fi o'ntẹ lu iyansipo Trump.

Ni ṣe ni o'n sọ ọrọ yi nipa NRA lati igba ti iṣẹlẹ iyinbọnpaniyan ti waye ni ile ẹkọ kan lọjọ kẹrinla oṣu keji ọdun yii ni Parkland, nilu Florida.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: