Ọyọ: Olubadan ni saa kẹta tọ si Ajimọbi

Gomina Abiọla Ajimọbi atawọn ẹsọ rẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Olubadan ati gomina Ajimọbi woju ara wọn lori ilana oye jijẹ nilu Ibadan

Olubadan tilu Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji ti ni ọpọ aseyọri Gomina Abiọla Ajimọbi ti ko lẹgbẹ lo mu ko yẹ lẹni ti yoo se saa min gẹgẹbii gomina.

Ọba Adetunji ni bi kii baa se ilana ofin to lee sediwọ eyi to fofin de awọn gomina lati mase se kọja saa meji, Gomina Ajimọbi yẹ ko see saa kẹta ni.

Olubadan sọrọ yi lọjọbọ nibi ipade kan ti gomina Ajimọbi pe awọn ọba alaye kan si jakejado ipinlẹ Ọyọ eyi to wa lati beere fun atilẹyin wọn fun ifẹsẹmulẹ alaafia ati eto aabo nipinlẹ Ọyọ.

Awọn aseyọri Ajimọbi wu wa lori

Nigba to nsọrọ, Olubadan ni, "Mo dupẹ lọwọ gomina nitori pe anri isẹ to ti se, taa si ngbadura pe ko ni koju aiseese."

"Yoruba kii mọriri ara wọn, wọn ko mọ ju ki wọn maa rọjo eebu, ki wọn si maa se ariwisi sugbọn ti eeyan kan ba se daada, o yẹ ka le sọ."

"Mo nsọ nipa nkan ti mo ti foju ri titi di akoko yi, o si wu mi ko lọ fun saa mii gẹgẹ bii gomina, ti kii ba se ofin ti ko lee faaye gbaa."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ọba Adetunji fi kun pe gomina Ajimọbi ti se daada pẹlu ọpọ aseyọri to ti se eyi to yẹ ka se sadankata si. Oriyin yi si lo ni yoo mu ko tubọ se aseyọri pupọ sii fun anfaani awọn eeyan ipinlẹ naa.