Aarẹ Trump ati Kim Jong-un ti gba lati jọ ṣe'pade

Aworan Trump ati Kim Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Trump ati Kim Jong-un ko fe imi ara wọn ri lakitan lenu ojo meta yi

Aarẹ Donald Trump orilẹẹde Amerika ati akẹgbe rẹ lati North Korea Kim Jong-un ti gba lati jo ṣe ipade.

Igbesẹ yi ni ọpọ ti ṣe apejuwẹ rẹ gẹgẹ bi ohun manigbagbe.0

Ile ijọba orilẹẹde Amerika fidi ọrọ mulẹ pe ipade naa yoo waye laye ati akoko ti awọn ko tii le sọ.

Aṣoju orilẹẹde South Korea kan, Chun Eiu yong ti o ti ṣe ipade pẹlu awọn olori mejeeji lọsẹyi lo sọ wi pe Aarẹ Kim ti gba lati dawọ duro lori didan ado oloro wo.

Ọgbẹni Trump fi ọrọ ṣọwọ lori oju opo ayelujara twita rẹ pe ohun ti oun gbọ lati ọdọ Kim Jong-un nii ṣe pẹlu didẹkun amulo ado oloro ṣugbọn o ni ijiya ti awọn gbe le North Korea yoo ṣi wa ni lẹ titi di igba ti ọrọ yoo fi wọ.

Ko si olori orilẹẹde Amerika kankan to ṣe ipade ri pẹlu olori orilẹẹde North Korea.

Ni nkan bi oṣu melo sẹyin ni awọn olori mejeeji ntako ọrọ sira wọn.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: