Awọn dokita nilu Australia fẹ f'ofin de ọti mimu f'ọdun marun

Aworan eni to'n mu ọti Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Tenant Creek ti ri alekun ninu iwa ipa ati gbigba ẹmi ara ẹni latari ọti amupara

Awọn onimọ eto ilera ni ilu kan to wa ni gbungbun Australia ti ke gbajare ki wọn f'ofin de ọti mimu f'ọdun marun.

Wọn ni ipe naa ṣe pataki ki ilu naa le jaja bọ lọwọ bi ọti mimu ti ṣe'n ṣ'okunfa alekun iwa ipa ati gbigba ẹmi ara ẹni.

Ilu naa ti ṣaaju ṣe agbekale ofin pajawiri ọlọsẹmeji pe ki awọn eniyan ma ṣe mu ọti lẹyin igba ti wọn ṣe akiyesi bi iwa ipa to tati ọwọ ọti mimu ti ṣe peleke ni ilu Tenant Creek.

Awọn dokita naa ṣ'alaye ọrọ ni iwaju ipade ara ilu ti wọn ṣe wi pe ọkẹ aimọye oloyun ti o ti mu ọti amupara ni awọn ṣe itọju wọn to fi mọ awọn eniyan ibilẹ to jẹ wi pe wọn ṣe ikọlu wọn tabi ti wọn gbiyanju ati gba ẹmi ara wọn.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si:

Related Topics