Arsenal na Watford ni 3-0

Mustafi gba bọọlu sinu awọn Image copyright Getty Images

Ẹgbe agbabọọlu Arsenal ti fẹsẹ wọn rinlẹ nipo kefa ninu atẹ igbelewọn liigi ilẹ Gẹẹsi pẹlu ami ayo 48 lẹyin igba ti wọn naa Watford pẹlu ami ayo mẹta s'odo.

Shkodran Mustafi lo kọkọ gba bọọlu sinu awọn nisẹju mẹjọ si igba ti wọn bẹrẹ ere.

Mustafi f'ori kan bọọlu sinu awọn nigba ti Mesut Ozil gba sile Watford.

Watford naa gbiyanju lati gbẹsan, sugbọn wọn ko le gba bọọlu sinu awọn Arsenal titi ti wọn fi lọ fun isimi ilaji asiko.

Nigba ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ lẹyin isimi ilaji asiko, Watford ko so ireti nu rara.

Nibi ti wọn tin gbiyanju ati gbẹsan ni Pierre-Emerick Aubameyang ti gba bọọlu sinu awọn Watford lẹyin ti Henrikh Mkhitaryan gba bọọlu si ọdọ rẹ.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Aubameyang gba bọọlu sinu awọn Watford lẹyin isẹju mọkandinlọgọta sigba ti wọn bẹrẹ ere

Ikọ agbabọọlu Watford ri anfani ati gbesan lẹyin ti wọn fun wọn ni ayo gbelẹ-ko-gba-sile (Penalty) gẹgẹ bi itaran fun ẹṣẹ ti agbabọọlu Arsenal kan ṣẹ.

Sugbọn Troy Deeney gba bọọlu na s'ọwọ Petr Cech to n ba Arsenal sọ le ni.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Petr Cech mu bọọlu gbelẹ-ko-gba-sile (Penalty) ti Watford gba

Nisẹju kẹrindinlaadọrin (76) ti wọn bẹrẹ ere ni Henrikh Mkhitaryangba bọọlu ẹlẹkẹta s'awọn Watford.

Aubameyang lo gba bọọlu si Mkhitaryan ko to gba bọọlu na sinu awọn Watford.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Aubameyang ati Mkhitaryan

Related Topics