Ileẹjọ Israel: Ẹ ko gbọdọ le awọn atipo mọ

Eeyan kan wa ninu sẹkẹsẹkẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Laarin ọdun 2006 si 2012 ni ọgọọrọ awọn eeyan lati ilẹ Afirika wọ de orilẹede Israel

Ileẹjọ giga kan ni orilẹede Israel ti gbẹsẹ le ipinnu ijọba orilẹede naa lati fi tipa tikuuku le ọkẹ aimoye awọn atipo lati ilẹ Afirika pada si ilẹ Baba wọn.

Ọpọ awọn atipo lati ilẹ Afrika to wa ni Israel ni wọn sa asala fun aabo ẹmi wọn wọn.

Idajọ yii n waye lẹyin ọjọ kan ti ijọba orilẹede naa ti kede wi pe oun yoo dawọ duro na lori igbesẹ naa titi di igba ti ileẹjọ naa ba gbe idajọ rẹ kalẹ ti oun yoo tun fi sisẹ lori awọn itakun ofin to so di ọna rẹ lori igbesẹ naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ileẹjọ ni ki ijọba duro naa ki wọn fi yanju igbẹjọ lori iwe ẹhonu to wa niwaju rẹ

Ileẹjọ naa gbe idajọ naa kalẹ ni idahun si iwe ẹhonu kan ti ọgọfa awọn atipo lati orilẹede Eritrea ati Sudan fọwọsi.

Ileẹjọ naa fun ijọba orilẹede Israel di ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹta lati fi fesi si iwe ẹhonu naa.

Amọsa, ileẹjọ naa pasẹ fun un lati fi igbesẹ naa ti sẹgbẹ kan naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orilẹede Isreal n gbero ati le awọn atipo to wa lati ilẹ Afirika

Amọ Igbakeji minisita fun ọrọ okeere, Tzipi Hotovely koro oju si idajọ ti ileẹjọ naa gbe kalẹ.

" Idajọ ti ileẹjọ gbe kalẹ loni jẹ eyi to n ka ijọba lọwọ ko lati yanju ọkan lara awọn isoro to n koju igbayegbadun orilẹede Israel."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Pupọ awọn atipo lati ilẹ Afrika lo wa ni orilẹede Israel

Pupọ awọn atipo lati ilẹ Afirika to wa ni orilẹede Israel ni wọn wa lati awọn orilẹede tijọba fami-lete-n-tutọ ti nwaye .

Pupọ wọn lo si jẹ wi pe aarin ọdun 2006 si 2012 ni wọn de ibẹ.