Arabirin Oklahoma yoo ṣẹwọn gbigbe ọmọ-birin-rẹ niyawo

Aworan iya ati ọmọ Image copyright Stephens County Jail
Àkọlé àwòrán Iya naa ati ọmọ rẹ ṣe igbiyawo l'ọdun 2016

Wọn ti ran Arabirin ipinlẹ Oklahoma kan l'Amerika to ṣe'gbaeyawo pẹlu ọmọ rẹ ni ẹwọn ọdun meji.

Patricia Ann Spann, eni dun marundinlaadọta (45), jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun fifẹ-ẹbi rẹ ati gbigbe ọmọ bibi inu rẹ, Misty Velvet Dawn Spann, ẹni dun mẹrindinlọgbọn (26), niyawo.

Iya naa padanu ẹtọ ati wo awọn ọmọ rẹ, sugbọn ọmọ-rẹ-birin pada s'ọwọ rẹ lọdun 2014.

Iya ati ọmọbirin naa ṣe'gbeyawo ninu oṣu kẹta ọdun 2016 lẹyin igba ti ofin ipinlẹ naa f'ayelẹ fun igbeyawo takọ-takọ ati tabo-tabo.

Awọn ọtẹlẹmuyẹ pada mọ wipe Patricia Ann Spann ti fẹ ọmọ-rẹ-kunrin ri.

Ọmọ-rẹ-kunrin, to jẹ ẹni ọdun mejidinlogun nigbanaa, tu igbeyawo naa ka l'ọdun 2010 lẹyin igba to gbe iya rẹ niyawo l'ọdun 2008.

Ajọ to n ṣeranwọ fun alaini l'Amerika lo s'awari wọn nigba ti n ṣe iwadi lori alafia awọn ọmọ kekere.

Gẹgẹ bi iwe-iroyin Oklahoman ṣe sọ, Misty Spann naa tu igbeyawo na ka ninu oṣu kewa ọdun to kọja lẹyin igba to sọ wi pe wọn tan oun jẹ si igbeyawo naa ni.

O sọ wi pe iya rẹ parọ wipe oun ti ba awọn agbẹjọro mẹta ọtọtọ s'ọrọ ti wọn si fii laya balẹ wi pe ko ni si ewu fun igbeyawo naa, gẹgẹ bi iwe-iroytin naa ṣe sọ.

Patricia Ann Spann sọ wipe oun nigbagbọ wi pe igbeyawo naa b'ofinmu nitoripe iwe-ọjọ-ibi ọmọ rẹ ko fi han wipe oun l'oun bi ọmọ naa, ati wi pe ọdun meji s'ẹyin l'oun ṣ'alabapade ọmọ ọhun.

Misty Spann jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun fifẹ-ẹbi rẹ ninu osu kọkanla ọdun to kọja, wọn si fun ni ọdun mẹwa ti wọn yoo fi ma wo iwa rẹ ti wọn yoo si fi ma fun ni imọran.

Lẹyin iye ọdun ti wọn ni yoo lo l'ẹwọn l'ọjọ Iṣẹgun (Tuesday), Patricia Spann yoo lo to ọdun mẹjọ ti wọn yoo maa yẹ ihuwasi rẹ wo.

Yoo si tun fi orukọ rẹ silẹ gẹgẹ bii ẹlẹṣẹ ibalopọ lẹyin igba ti wọn ba tu silẹ tan.

Ninu ofin ipinlẹ naa , irufin ni keyan o fẹ ẹbi rẹ, koda bi wọn ko ba barawọn l'ajọṣepọ.