Inec yoo tẹsiwaju pẹlu pipe Sẹnẹtọ Melaye pada

Asofin Dino Melaye Image copyright @dinomelaye
Àkọlé àwòrán Asofin Melaye ti figba kan korin 'Ajekun Iya' si awọn alatako rẹ ri ni ọdun 2017.

Ajọ Inec to n s'eto ibo ni Naijiria yoo tẹsiwaju pẹlu ipepada Sẹnẹtọ Dino Melaye to n s'oju iwọ-oorun Kogi nile igbimọ asofin agba gẹgẹ bi ile ẹjọ ṣe sọ.

Oludari ipolongo ati ẹkọ oludibo ni ajọ Inec, Ọgbẹni Oluwole Osaze-Uzzi, lo sọ eleyi di mimọ nigba to n ba amohunmọworan Channels sọrọ.

Ọgbẹni Osaze-Uzzi sọ wi pe: "Ni bayii wọn ti gbe gbogbo igi-idina ofin kuro lọna, ajo naa yo si tẹsiwaju bi ẹni wi pe ọrọ ile ẹjọ ko ṣẹlẹ ri."

Awọn oludibo iwo-oorun Kogi ti kọkọ f'ọwọ si wi pe ki wọn o pe sẹnẹtọ naa pada.

Inec si bẹrẹ ipepada naa, sugbọn Melaye lọ si ile ẹjọ lati da ipepada na duro, amọsa o kuna nile ẹjọ naa.

Lẹyin igba naa lo sọ wi pe ẹjọ ti ile ẹjọ naa da ko tẹ oun lọrun.

Sugbọn ile ẹjọ to gbẹjọ naa lọ sọ wi pe ki ajọ Inec ma ba iṣẹ rẹ lọ.

Ninu ẹjọ ti wọn da lọjọ Ẹti, awọn adajọ ile-ẹjọ naa l'aAbuja sọ wi pe ẹjọ ti Mẹlaye gbe wa ko l'ẹsẹ nlẹ.

Akoroyin BBC gbiyanju lati gbọ tẹnu Dino Melaye, sugbọn asofin na ko gbe ipe to fi s'ọwọ si ẹrọ-ibani-sọrọ rẹ.