Wo fidio 'ọgba ẹwọn idẹra'

Wo fidio 'ọgba ẹwọn idẹra'

L’ọpọ igba, wọn maa n s’apejuwe ọgba ẹwọn Halden to wa l’orilẹede Norway gẹgẹ bi eleyi to n dẹ awọn ẹlẹwọn lara ju.

Awọn ẹlẹwọn le kọrin, kọ iṣẹ kafinta, wọn si le dana funrawọn, eleyi to n ṣ’eto bi wọn yoo ṣe ṣe ti wọn ba jade lẹwọn.

Botilẹ jẹ wipe, wọn n tako pe o n dẹ awọn ẹlẹwọn lara ju, Norway jẹ ọkan lara awọn orilẹede diẹ ti iye awọn ti wọn maa ṣẹ s’ofin lẹyin ti wọn ba kuro l’ọgba ẹwọn ti kere ju.