TY Danjuma ati ologun Naijiria tako arawọn

Ajagunfẹyinti Theophilus Yakubu Danjuma Image copyright TY Danjuma Private Office
Àkọlé àwòrán Ajagunfẹyinti Theophilus Yakubu Danjuma ni ologun Naijiria parapọ mọ awọn ọlọṣa

Ajagun f'ẹyinti Theophilus Yakubu Danjuma ati ileesẹ ologun Naijiria tako arawọn lori awọn ikọlu to n ṣẹlẹ ni Naijiria.

L'ọjọ Abamẹta ni Theophilus Danjuma sọ pe ologun Naijiria ko lati dẹkun ipaniyan to n waye ni Naijiria nitori pe awọn ologun naa l'ọwọ n bẹ.

Nigba ti o n sọrọ nibi ayẹyẹ igba-oye ile-ẹkọ giga yunifasiti ipinlẹ Taraba, ajagunfẹyinti Danjuma ni awọn ologun n fi ikan kẹ kan.

O s'afikun wipe awọn olologun n lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọlọṣa lati pa awọn ọmọ Naijiria.

Image copyright Getty Images

Ọgbẹni Danjuma, to jẹ minisita fun eto aabo tẹlẹ ri, kesi awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn o daabo bo arawọn.

Sugbọn agbẹnusọ fun ileese ologun, Texas Chukwu, sọ pe gbogbo ẹni ti wọn ba ka ọhun ija mọ l'ọwọ yoo f'oju wina ofin.

Atẹjade kan ti ọgagun Chukwu gbe jade sọ pe awọn ko fẹ ba Danjuma jiyan sugbọn ko si otitọ ninu ọrọ to sọ nipa ologun Naijiria.

O s'afikun wipe ologun Naijiria ti padanu awọn ọmọ-ogun nibi to n ti n gbiyanju ati ri pe alafia jọba nipinlẹ Taraba.

O s'apejuwe pe wọn bẹ ọmọ ogun kan lori ni ilu Takum nipinlẹ Taraba l'ọjọ kẹrindinlogun (16) , osu kẹta, ọdun 2018.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajagunfẹyinti Danjuma figba kan jẹ ọgagun ni ileesẹ ologun Naijiria ri

O ni lati igba ti ikọ ko-gberegbe Ex AYEM AKPATUMA ti bẹrẹ isẹ ati dẹkun ikọlu l'agbegbe ọhun, ni ijọba ipinlẹ Taraba ti kọ jale lati f'ọwọ s'ọwọ pọ pẹlu wọn.