Ina Russia: Awọn ọmọde sọnu sinu ijamba ina ile itaja

Aworan ibudo itaja ni Kemerovo Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ile itaja ti ina naa ti seyo ni sinima ati ile ounje to pọ

Okere tan, eniyan mẹtadinlogoji lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ina kan to waye ni ibudo itaja kan ni ilu Kemerovo lorilẹede Russia.

O to eniyan mẹrinlelọgọta ti wọn ko ri, ti a si gbọ wi pe, ọmọde mọkanlelogoji wa ninu wọn, nigba ti awon apa kan wa ninu ewu pe ibudo itaja naa le ya lule.

Ina naa bẹrẹ nibi to ga ju ninu ile itaja Winter Cherry nigba ti ọpọ eniyan n woran ni aaye sinima.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Fidio ti awọn eniyan fi sọwọ sori ẹrọ ayelujara lọjọ aiku se afihan bi awọn eniyan ti se'n bẹ jade lati oju ferese lati doola ẹmi wọn.