Fayose: Ojuti nla ni aawọ nipa ibiti Leah Sharibu wa

Aworan Ayo Fayose Image copyright Facebook/Lere Olayinka
Àkọlé àwòrán Ayo Fayose je alatako to foju han si ijọba orilẹẹde Naijiria

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ni, idojuti nla ni bi ileesẹ ọlọpa Naijiria ko ti se ni iroyin to peye nipa akẹkọ Dapchi kan to sẹku ti wọn ko tii ri.

O ni eyi se afihan aigboraẹniye to wa ninu ijọba to wa lode.

Loju opo Twitter rẹ loti lede ọrọ naa.

O tesiwaju pe idojuti nla ni ki ọga ọlọpa wa si ori ẹro amohunmaworan apapọ lati tan ara ilu jẹ lori iroyin ti ko daa loju.

''Bi ọga ọlọpa ko ti se ni iroyin to peye lori Boko Haram, safihan bi darudapọ ti se gbode kan labe ijọba yi. Eyi mu ka gbosuba fun ọrọ ti minista fun eto aabo nigba kan ri, ajaagunfẹyinti Theophilus Danjuma so pe, ki awọn ọmọ orilẹẹde yi wa wọrọkọ fi sada lori pipese aabo fun ara wọn nitori pe ijọba to wa lode yi ko mo odo ti yoo da ọrunla si, nipa didabo bo ara ilu''

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Lai pe yi ni ọga ọlọpa ni Naijiria, Ibrahim Idris, tako ọrọ ti awọn ileese iroyin kan gbe jade pe, oun sọ pe, ijọba yoo gbe akẹko Dapchi kan to ku pada wale laipe.