Ìsẹ̀lẹ̀ iná Venezuela: Ẹ̀mí 68 bọ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá Valencia

Aworan Awọn molebi to n sunkun Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn molebi faraya nitori isẹlẹ naa ni iwaju agọ ọlọpaa

Awọn alasẹ ni ilu Valencia nipinlẹ Carabobo, lorilẹẹde Venezuela so pe ifẹhonu han ati ijamba ina ni agọ ọlọpaa kan ti sokunfa ki ẹmi mejidinlaadọrin bọ.

Olupẹjo agba fun ijọba, Tarek Saab ni, iwadi yoo bẹrẹ ni kia kia lati tọpinpin ohun to fa ijamba naa.

Wọn ni ijamba ina naa bẹrẹ lọjọru nigba ti awọn ẹlẹwọn kan sọ ina si ibusun wọn, ki wọn ba le ri ọna sa jade.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ọlọpaa lo afẹfẹ tajutaju lati tu awọn mọlebi to yi ago ọlọpaa naa kaa, lẹyin ti wọn gbo iroyin ijamba ina naa.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn molebi ati ara adugbo suru bo ọkọ ọlọpaa

Osise ijọba kan, Jesus Santander, fidi ọrọ naa mulẹ pe ọlọpaa kan fara gbọta ninu isẹlẹ naa eleyi ti wọn ti dẹkun rẹ.

O ni ijọba ipinlẹ Carabobo n topinpin isẹle naa.