Àbọ̀ Malala Yousafzai: Ó padà sílé lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí wọn yìnbọn mọ́ọ

Aworan Malala Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọ ọdun meedogun ni Malala nigba ti won yinbọn mọ

Alami ẹyẹ alafia lagbaye nni, Malala Yousafzai, ti pada si orilẹẹde rẹ, Pakistan fun igba akọkọ, lẹyin tawọn ikọ Taliban yinbọn lu.

Arabinrin Yousafzai, to ti to ẹni ogun ọdun bayi, farapa lọdun 2012 nigba ti ikọ Taliban yinbon lu u, fun bi o ti se'n polongo eto ẹko fun awọn ọmọbinrin.

Ireti wa wi pe yoo se ipade pẹlu olootu ijọba ni pakistan, Shahid Khaqan Abbasi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAyajọ ọjọ ololufẹ ma n waye lọjọ kẹrinla, osu keji ọdun

Osise ijọba kan so fun ile ise iroyin AFP pe ''wọn se irinajo naa ni bonkẹlẹ nitori ewu to rọ mọ ọ''

Ile isẹ amounmaworan orilẹẹde Pakistan se afihan fidio kan, ti o jo pe a ti ri Malala ati awọn obi rẹ ninu rẹ pẹlu awọn ẹlẹso abo ni papako ofurufu Benazir Bhutto nilu Islamabad.

A gbo iroyin pe irinajo naa ko ye ko ju ọjọ mẹrin lo.

Inu ọpọ eeyan dun si ipadabọ Malala

Ọ́pọ fi idunnu wọn han lori twitter nigba ti wọn gbo iroyin pe Malala dari pada wale.

Ko ti daju boya yoo se abẹwo si idile rẹ to wa ni ilu Swat ni iwọ oorun ariwa orilẹẹde naa.

Related Topics