Iléeṣẹ́ ọlọ́pa nipinlẹ Ọ̀ṣun ṣe àfihán ibọn 86 ti wọn gba

Aworan Ibọn Image copyright POLICE OSUN COMMAND
Àkọlé àwòrán Ọga ọlọpaa Olafimihan Adeoye ni ọpọ finufẹdo jọwọ ibọn wọn

Iléeṣẹ́ ọlọ́pa nipinlẹ̀ Ọ̀ṣun ti ṣe àfihan àwọn ìbọn oríṣiríṣi tó tó mẹ́rìndínláàdọ́rùnún ati ọta ìbọn tó tó méjídínláàdọ́rùnún.

Ni olu ilu ipinlẹ ọ̀hun, Oṣogbo, ni wọn ti fí àwọn ìbọn náà han àwọn akọ̀royin.

Oláfimíhàn Adéóye to jé òga ọlọ́pa ni ipinlẹ náà ni ìgbese náà wa ni ìbámu pẹ̀lu àṣe ọ̀ga ọlọ́pà patapata, Ibrahim Idris to ni kí àwọn ara ilu jọ̀wọ̀ ohun ìjà wọn fun ile iṣẹ ọlọ́pa.

Image copyright POLICE OSUN COMMAND
Àkọlé àwòrán Àwọn ìbọn na wa loríṣiríṣi

Nise ni o parọwa si awọn ara ilu lati "tawọn lolobo ti wọn ba ri enikẹni to ni ohun ija lọwọ. ''