Iléejọ́ Brazil: Luiz Lula yóò f‘ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá jura

Aarẹ Lula

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹsun ikowoje ni wọn fe tori e ran Aarẹ Lula lẹwọn

Ile ẹjo to gaju lọ ni Brazil ti dajọ ẹwọn fun Aarẹ ana orilẹẹde naa, Luiz Inacio da Silva Lula.

Wọn dajọ pe o gbọdo bẹrẹ ẹwọn ọlọdun mejila naa ni dandan n dandan.

Awọn adajọ to gbẹjo re lori ẹsun ikowoje kọ lati gbọ gbogbo ẹbẹ awọn agbẹjọro rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn alatako Aare Lula se iwọde ni iwaju ile asofin lorileede Brazil

Igbese naa je ifasẹyin to lagbara fun olori oloselu apa osi naa, ti ọpọ ti lero wi pe yoo rọwọ mu ninu idibo Aare ti yoo waye losu kẹwa ọdun yi.

Ẹjo naa ti mu ki ero awọn eeyan se otooto lorileẹẹde naa pẹlu bi orisirisi iwọde lati ọwọ awọn alatilẹyin ati alatako rẹ se n waye.