Ìwé ‘Things Fall Apart’ pé ọgọ́ta ọdún

Ìwé Things Fall Apart Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọ́n ti ta mílíọ́nù méjìlá ìwé náà lágbàáyé

Ìwé ‘Things Fall Apart’ tí Chinua Achebe kọ jẹ́ ìdánwò fún àsà àwùjọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ gẹ́gẹ́ bó se ń wáyé lásìkò ìjọba amúnisìn.

Ọdún 1958 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ ìwé náà jáde, tí wọ́n sì ti tú ìwé náà sí àádọ́ta èdè jákèjádò àgbáyé.

Wọ́n ti ta mílíọ́nù méjìlá ìwé náà lágbàáyé.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdún 1958 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ ìwé náà jáde

Lọ́nà áti sàmì ayẹyẹ ọgọ́ta ọdún tí wọn kó ìwé náà síta, ló mú kí àwọn òsèré tíátà nílẹ̀ adúláwọ̀, àwọn òǹkọ̀wé àtàwọn aronújinlẹ̀ se péjọ pọ̀ fún ètò kíka gbogbo ìwé náà lójú táyé.

Ibùdó London South Centre sì ni ètò náà ti wáyé.

Akọ̀ròyìn BBC, Kim Chakanesta náà kò gbẹ́yìn níbẹ̀, tó sì fi ọ̀rọ̀ wá àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ lẹ́nu wò nípa èrò wọn lórí ìwé Things Fall Apart.

Ẹ gbọ ẹ̀dà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà tó se fún Adesua Etomi, tíí se ìlúmọ̀ọ́ká òsèré tíátá àti gbajúgbaja òǹkọ̀wé nnì, Chibundi Onusọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdesua Etomi: Ìwé Things Fall Apart yááyì púpọ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌwé Things Fall Apart: Ìwé àkàtúnkà ni