Ṣé lóòótọ́ ní àwọn ọdọ́ Nàìjíríà kò fẹ ǹkan ṣe?

Aworan Aarẹ Buhari Image copyright TWITTER/GOVERNMENT OF NIGERIA
Àkọlé àwòrán Kii se igba akọkọ re ti Aare Buhari yoo so ọrọ to ma da awuyewuye silẹ

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí ènìyàn bá ta ará ilé rẹ̀ lọ́pọ̀, ó seése kó má rí i rà lọwọ́n. Àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti n faraya lójú òpó Twitter lóríi bí Ààrẹ Buhari ṣe sọ wípé àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà kò fẹ ǹkan ṣe.

Buhari sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí o n sọrọ níbi ìpàdé Commonwealth ní Westminster lọjọru ọsẹ.

Ninu fanran fidio kan to wa lori Youtube, Buhari ni ''Iye awọn ọdọ orileede Naijiria to ida ọgọta. Ọpọ ninu wọn ni ko si lọ si ile ẹkọ. O ní àwọn ti ko nisẹ lọwọ ninu wọn n joko silẹ lai se nnkankan ti wọn si n sọ wi pe nitori pé Naijiria jẹ orileede to nri owo nidi epo rọbi, o yẹ ki ijọba fun awọn ni ile ọfẹ, ẹkọ ọfẹ ati ilera ọfẹ''

Esi ti awọn eeyan fun un pada lori Twitter ko rẹrin rara.

Koda, gbajugabaja oloselu kan ti oun naa fẹ du ipo Aarẹ, Atiku Abubakar, da si ọrọ ọ̀hún.

Gomina ipinle Ekiti, Ayodele Fayose ti ko fi igba kan ma salai tako ijọba Buhari naa ko gbeyin.

Awọn agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari ko tii fesi si ọrọ naa.

Lọwọlọwọ, Aarẹ Buhari wa ni ilẹ̀ Gẹẹsi nibi ti o ti n kopa ninu ipade àgbáríjọpọ̀ àwọn orílẹ̀èdè tó gba ominira lọwọ ile Geesi ti a mo si Commonwealth.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: