Ìgbà máàrún tí ọ̀rọ̀ Buhari dá awuyewuye sílẹ̀

Image copyright ERIC PIERMONT/AFP/GETTY
Àkọlé àwòrán Ajagun fẹyinti ni Buhari to ti wa di Aarẹ labe ijọba tiwantiwa ni Naijiria

Lati ọdún bíi mẹta tí ààrẹ Muhammadu Buhari ti wa lori aleefa, o ti ṣe awọn ohùn manigbagbe kan bẹẹ sì ní o sọ awọn ọrọ manigbagbe naa.

Laipẹ yii o sọ wípé àwọn ọ̀dọ̀ Nàìjíríà ko fẹ nkan ṣe, tí ọrọ náà sì mú ariwisi ọtọọtọ wa.

Ẹ jẹ ki a wo awọn igba miran to sọ ọrọ ni ilu okeere tó dá awuyewuye silẹ, pàápàá jùlọ lórí ẹrọ ayélujára.

"Yara inu laaye Aisha wa"

Nigba to se abẹwo kan si orileede Germany, Aarẹ Buhari sọ fun olootu ijọba orileede naa, Angela Merkel, pe'' iyara inu laaye iyawo oun wa.''

Image copyright JOHN MACDOUGALL/AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Esi ti Buhari fọ si ibeere naa ya ọpọ eniyan lẹnu

Aisha Buhari ti saaju sọ wi pe bi ọkọ ohun ba gbe apoti ibo,oun ko ni dibo pẹlu bi nnkan se'n lọ ni ijọba rẹ.

Titi di bi a se nsọrọ yii, awọn ọmọ Naijiria ko gbagbe ọrọ naa.

"Loot ni iwa jẹgudujẹra gbil ni Naijiria"

Àkọlé àwòrán Buhari ni ko si irọ ninu nnkan ti Cameron sọ nipa Naijiria

Olootu ijọba ilẹ̀ Gẹẹsi, David Cameron sọ nibi ipade kan to da lori iwa jẹgudujẹra, pe orilẹede Naijiria wa lara awọn ti o gbajugbaja ninu iwa naa.

Ọrọ naa bi awọn ọmọ Naijiria ninu, sugbọn eyi to da awuyewuye silẹ ni esi Aarẹ Buhari pe lootọ ni Naijiria gbajugbaja ninu iwa jẹgudujẹra.

"Awọn ọdọ ko fẹ nkan se"

Eyi ni ọrọ to sẹ̀sẹ̀ sọ to mu ki ọpọ ọdọ Naijiria faraya lori ikanni Twitter.

Image copyright TWITTER/GOVERNMENT OF NIGERIA
Àkọlé àwòrán Kii se igba akọkọ re ti Aare Buhari yoo so ọrọ to ma da awuyewuye silẹ

Alaye ni Buhari ni oun n ṣe lori ibeere kan ti wọn fi sọwọ sii nibi ìpàdé Commonwealth ní Westminster lọjọru, sugbọn ọrọ to sọ ko dun mọ awọn ọdọ Naijiria nínú, o ni ''won o fe nkan se''

Awọn eyi to sọ nile

Pẹlu bi aibalẹ ọkan se wa, nitori ija awọn darandaran ati awọn agbẹ ni ipinlẹ Benue, Aarẹ Buhari lọ se ipade pẹlu awọn alenulọrọ ni ipinlẹ naa.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba to sọfun awọn to wa ni ikalẹ pe, oun ko mọ pe ọga ọlọpaa, Ibrahim Idris kọ etiikun si aṣẹ t'oun pa, pe ko k'ẹru rẹ lọ si Benue.

Image copyright Twitter/Mbuhari
Àkọlé àwòrán Buhari ti saaju pasẹ fun ọga ọlọpa ko kẹru rẹ lọ si Benue

AfCFTA: Naijiria k lati t'ọwọ bọ iwe ilana okoowo tuntun fun Afrika

Ohun ti ọpọ eniyan sọ ni wi pe bi Naijiria ti o jẹ ọkan gboogi lara awọn orilẹede ti karakata rẹ muna doko ju nilẹ Afrika, bi ko se kopa jẹ ipenija fun adehun naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bi Naijiria ti o jẹ kan gboogi lara awọn orilẹẹde ti karakata rẹ muna-doko nilẹ Afrika ko se kopa jẹ ipenija fun adehun naa.

Lẹyin ti ipade naa pari ni Rwanda, ti wọn si ti f'ọwọ si iwe tan, ni Aarẹ Buhari wa se akojọpọ igbimọ kan nibi ipade igbimọ alasẹ ijọba orilẹede Naijiria.

O ni ''o yẹ ki ijọba tubọ se agbeyẹwo atubọtan titọwọ bọ iwe adehun naa lori ọrọ aje ati eto aabo l'orilẹede Naijiria.''