Adigunjalè pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Zamfarà

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adigunjalè pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Zamfarà

Àwọn agbébọn kọlu ìlú Kabaro àti ìlú méjì míì ní ìjọba ìbílẹ̀ Maru, ìpínlẹ̀ Zamfara lápá ìwọ̀ oòrùn àríwá orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Àwọn olùgbé ìlú náà àtàwọn ọlọ́pàá fí àrídájú hàn wípé wọn kò tíì mọ iye ènìyàn tó bá ìsẹ̀lẹ̀ náà rìn.

Àwọn adigunjalè náà gun kẹ̀kẹ́ alupùpù bí wọ́n se pọ̀ tó wọ ìlú Kabaro, ilu Danmani Hausawa àti Danmani Dakarkari.

Kò fibẹ́ẹ̀ tíì sí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn ìsẹ̀lẹ̀ náà sùgbọ́n ará ìjọba ìbílẹ̀ Maru kan tí kò fẹ́ kí a dá orúkọ rẹ̀ nítorí àbò sàlàyé wípé àwọn adigunjalè ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ ọsẹ́ ní ìlú Kabaro lálẹ́ ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ kí wọ́n tó tún sí l sí Damani Hausawa àti Damani Dankarkari lówurọ̀ ọjọ́bọ̀.

Ìròyìn jẹ́ kó di mímọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n pá ní ìlú kọ̀ọ̀kan tí wọ́n sì gbé ọ̀pọ̀ míì tó fara pa lọ sílé ìwòsàn.

Alukoro ilé isẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Zamfara, Shehu Mohammed sọ wípé "òótọ́ ni pé ìkọlù wáyé ní àwọn ìlú mẹ́ta ní ìjọba ìbílẹ̀ Maru. Mi ò le sọ iye ènìyàn tó gbẹ́mí mì sùgbọ́n a sì ń gbìyànjú láti mọ̀ ọ́. A ti rán àwọn èèyan wa lọ́ sí àwọn ibi tí wọ́n kọlù... A ńsa ipá wa a ó sì tẹ̀síwájú láti dá àbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn.

Àbẹ̀wò ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ náà láti fi dá àwọn ará ìlú lójú pé àbò wà kò sì tíì dáwọ́ ìkọlù yìí dúró.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Related Topics