Ọ̀mọ ọbabìnrin Elizabeth ri ìran ìkẹrin ẹ̀

The Duke and Duchess of Cambridge and their two children Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Catherine bí ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀ka Lindo ní ilé ìwòsàn St Mary ní London ní ọjọ́ ajé.

Catherine Middleton tí ó jẹ́ ìyàwó obalọ́la ti ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì, Omooba William, ti bí ọmọ ọkùnrin.

Ọmọ náà tí ó jẹ́ àbíṣèkẹta Catherine àti William, nì ó jẹ́ ìkaàrún sórí ìtẹ́.

Catherine bí ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀ka Lindo ní ilé ìwòsàn St Mary ní London ní ọjọ́ ajé.

Ààfin Kensington, ibùjókòó William àti aya rẹ̀ sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé àlàáfíà ni Catherine àti ọmọ rẹ̀ wà.

Wọ́n sọ pé, William tilẹ̀ wà níbẹ̀ nígbà tí aya rẹ̀ bí ọmọ náà.

Àárọ̀ kùtù ọjọ́ ajé ni a gbọ́ pé obi bẹ̀rẹ̀ sí ń mú Catherine, tí wọ́n sì gbe lọ ilé ìwòsàn.