Ère tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó mọ fún olóògbé Gani Fawẹ̀hìnmí

Ère tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó gbẹ́ fún olóògbé Gani Fawẹ̀hìnmí Image copyright @followlasg
Àkọlé àwòrán Ìjọba ìpínlẹ̀ yẹ́ olóògbé Gani Fawẹ̀hìnmí sí pẹ̀lú ère yìí

Gómìnà Akínwùmí Ambodé ti ìlú Èkó lọ́jọ́ àìkú rọ àwọn ọ́mọ́ Nàìjíríà láti kọ́gbọ́n látara ìwà àti àpẹrẹ́ rere ti ìgbà ayé olóògbé Gani Fawẹ̀hìnmí.

Ó rọ̀ wọ́n láti se èyí pẹ̀lú dídojú ìjà kọ isẹ́ kí wọ́n sì mú ìlọsíwájú bá ìlú fún ànfàní àwọn ìran tó mbọ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Ambodé ẹni tí igbákejì rẹ̀ Idiat Adebule sojú fún funpè yìí níbi tí wọ́n ti sí asọ lójú ère olóògbé Fawẹ̀hìnmí tí wọ́n mọ sí àgbègbè Liberty Park, Ọjọ́ta n'ilú Èko.

Image copyright @followlasg
Àkọlé àwòrán Ibi ìsíde ère tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó mọ fún olóògbé Gani Fawẹ̀hìnmí

Wọ́n se sísí asọ lójú ere yìí ní ìrántí ayẹyẹ ọjọ́ íbí lẹ́yìn ìpapòda ajàfẹ́tọ̀ọ́ ará ìlú olóògbé náà.

Àkọlé àwòrán Ǹjẹ́ ère yìí jọ Gani Fawẹ̀hìnmí?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ère yìí yẹ́ Bàba sí, wọ̀nyìí ni ohun tí àwọn ènìyàn ńsọ́ lórí òpó Twitter nípa rẹ̀:

Ẹ̀wẹ̀, àwọn míì kan sárá sí isẹ́ takuntakun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó se yìí:

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọ Nàíjíríà: Àrímáleèlọ ni àríyá alẹ́ sátidé BB Naija