Òrọ̀ àtìlẹyìn Kanye West sí Trump ti dá wàhálá sílẹ̀

Donald Trump ati Kanye West Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn kan ti lẹ̀ sọ wí pé ọgbọ́n láti ta àwo orin rẹ̀ fún àwọn tí ó fẹ́ràn Trump ni.

Ṣe olórin aláwọ̀ dúdú ilẹ̀ Amerika nì, Kanye West, fẹ́ fi Trump ta ọjà ni?

West ti dá aáwọ̀ sílẹ̀ láàrín àwọn olólòfẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó kọ ọ̀rọ̀ àtìlẹ́hìn fún Ààre Donald Trump lórí Twitter ní Ọjọ́bọ.

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú orílẹ̀-ede náà ni kò fẹ́ràn Trump, fún ìdí èyí, púpọ̀ nínú àwọn tí ó dá sí ọ̀rọ̀ náà jẹ́ aláwọ̀ dúdú, wọ́n bẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ olórin náà.

West fi ìfẹ́ pípé tó ní sí Trump hàn, ní èyí tí Trump náà fèsì ọpẹ́ sí padà

Kanye West tún fi hàn pé inú rẹ̀ kò dùn sí ààrẹ àná ní orílẹ̀-èdè náà, Barack Obama.

Èyi ló wá mú inú bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú orílẹ̀ èdè náà.

Àwọn kan ti lẹ̀ sọ wí pé ọgbọ́n láti ta àwo orin rẹ̀ fún àwọn tí ó jẹ́ olólùfẹ́ Trump ni ó ń dá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: