Ìwọnba èèyàn perete lo jáde fun ìgbésẹ̀ láti yo Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye

Aworan eto idibo Image copyright TWITTER/INEC
Àkọlé àwòrán INEC ni ètò náà lọ ní irọwọrọse.

INEC ti bẹ̀rẹ̀ àkójọpọ̀ èsì àyẹ̀wò orúkọ èèyàn to kópa ninu igbésẹ̀ àti yọ Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye ni ilé ìgbìmọ aṣòfin àgbà.

INEC fi aworan bi nnkan se n lo si oju opo Twitter wọn.

Sugbọn Ìròyìn to tẹ̀ wa lọwọ láti awon ẹkùn ìdìbò ti àyẹwò orúkọ tí n wáyé sọ pe iriri oríṣiríṣi lo n wáyé níbẹ̀.

Usman Okai ti o je oníròyìn abele ni ilu Lokoja sọ pé láwọn ibùdó ìdìbò tí òun ṣe àbẹwò sí gẹgẹ bíi èyí tó wà ni Mopamuro, Lokoja àti ibùdó ìdìbò tó wà ni ilé ẹ̀kọ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ Kogi, ìgbésẹ náà kò múná dóko.

"Gbogbo ìsèlè yìí dàbí eré tíátà láàrin Gómìnà àti Senato Dino. Ni àwọn ibùdó ìdìbò kan,àwọn àgùnbánirọ̀ nìkan ní wọn dá joko síbẹ.''

Nínú fanran fidio kan ti o fi ṣọwọ́ sí oju opo Facebook, a rí i ti awọn kàn n yẹ orúkọ tó wà lórí àkọsílẹ wò ti wọn sì ni eniyan kan lo bọwọ luwe ọ̀pọ̀ orúkọ.

Awọn to forukọ silẹ nikan lọrọ kan

Olori ẹka tó n risi eto idanilẹkọ awọn oludibo ni ìpínlè Kogi, Ahmed Bagudu Biambo ni ètò náà n lọ ní irọwọrọse.

O ṣàlàyé pé pàtàkì ìgbésẹ náà ni pé àwọn fẹ fìdí àwọn ojúlówó oludibo múlẹ ṣáájú ìdìbò ti yóò wáyé.

''ẹnikẹni tí kò bá f'ọwọ́ sí ìwé lati pe Sẹ́netọ̀ Dino padà ko ni láti yọjú síbi àyẹwò orúkọ.''

Image copyright Twitter/INEC
Àkọlé àwòrán Awọn ti wọn ba se ayẹwo kaadi idibo wọn ni INEC yóò gba oruko wọn silẹ

O tẹsiwaju pe awon ti orúkọ wọn bá wà níbè, ''àwọn oṣiṣẹ wa yóò lo ẹrọ tó n yẹ kaadi wo lati se ayewo pé àwọn ni wọn ni kaadi naa.''

Lẹyin gbogbo rẹ, o ni awọn yóò gbà ''gbogbo orúkọ àwọn to buwọ́lù ìwé tí aṣoju INEC yóò sì kéde iye eniyan to kópa.''

Dino Melaye ni Sẹ́netọ̀ to soju fun ẹkùn ìdìbò ìwọ̀-oòrùn ìpínlẹ̀ Kogi.