LASEMA: Ètò ìgbáradì ló fa súnkẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ ní ìlú Èkó

Aworan ọkọ to jasomi Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán LASEMA ni igbaradi náà wáyé láti mọ bi ibasepọ ti ṣe wa láàarin àwọn ẹka ìjọba lati kojú ìṣẹlẹ pajawiri

Àlàyé tí wáyé lórí òun tó fà sún kéré kere fakere ọkọ tó ṣẹlẹ l'owurọ ọjọ ìsinmi lórí afárá 3rd Mainland.

Ile iṣẹ tó n mójú tó ìṣẹlẹ pàjáwàrì ní ìpínlè Eko, Lasema ni ki se ijamba ọkọ lo faa bi ki ṣe ètò igbaradi ati àyẹwò irinṣẹ fún kíkọ ju ìṣẹlẹ pajawiri tawọn se.

Nínú ọrọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ igbaradi to wáyé, oga ile iṣẹ Lasema, Tiamiyu Adeshina ti alukoro Lasema, Adebayo Kehinde, je isẹ rẹ ni ''igbaradi náà waye láti mọ bi ibasepọ ti ṣe wa láàrin àwọn ẹka ìjọba nipa kikojú ìṣẹlẹ pajawiri''

"Kò sí ifoya. A mọmọ ṣe ìgbáradì yi ki musemuse àwọn òṣìṣẹ́ wa le gba musẹ si ní.

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán LASEMA ati awọn ile ise pajawiri yo ọkọ ti o jasosa lati ṣe afihan ìṣẹlẹ pajawiri

Á gbo pe Lasema ati awọn àjọ míràn ni won jọ pawọpọ ṣe ètò ọhun ti wọn pe ni ''ọkọ jasosa."

Fún wákàtí mélòó kan, ìgbáradì náà dá súnkẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ si lẹ̀.

Ọpọ ará ìlú ní kò mọ nípa ìgbáradì náà ti àwọn tó kọjá níbè sí fi ọrọ sí ojú òpó Twitter pé ìjàmbá ọkọ ló wáyé lórí afárá 3rd Mainland.

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Wọn ṣe afihan bi wọn yoo ti gbe awọn to farapa lo si ile iwosan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: