Ọ̀ògùn ikọ́ codeine ń pa iran kan run lọ ní Nàíjíríà

Àwòrán ọmọdébìnrin tó kúndùn oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine
Àkọlé àwòrán Oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine ń se àkóbá fún ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà ní ìsọ̀rí ń sọ̀rí

Nígbà tí àbúrò Ruona Meyer to jẹ́ ọkùnrin, di ẹni tó kúndùn oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine nínú, ló mú kí Ruona bẹ̀rẹ̀ sí ní se ìwádìí àwọn ọkùnrin tó ń se oògùn ikọ́ olómi yìí ní ìgboro ìlú Èkó.

Ìwádìí yìí ló gbée dé agbègbè tí agbami ìwà ọ̀daràn ti ń wáyé ní orílẹ̀èdè Nàíjíríà, tó sì se àkọsílẹ̀ ìwà ọ̀daràn tó ń tàn kálẹ̀ bíi ọ̀wàrà òjò, èyí tó ń ba ayé àwọn ọ̀dọ́ jẹ́ jákèjádò ẹkùn ìwọ̀ òòrùn Afrika.

"Níbití ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wà, ní kété tí wọn bá ti tọ́ adùn oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine nínú wò, ni wọn yóò máa yọ ọ́ lẹ́nu láti mu síi."

Ní kété tí mo gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ló rẹ̀ mí wá láti inú.

Èmi gan ti fojú rí ohun tó ń sọ - ọ̀pọ̀ ọ̀dọ̀ Nàíjíríà ni oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine nínú ti di bárakú fún, èyí tó leè di kòsee-mámu fún wọn. Ọmọdé-bìnrin, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan, tó wá láti ìlú mi, tíí se ìlú Èkó, ni ọkàn àwọn òbí rẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì, tí wọn kò sì mọ ọ̀nà tí wọn leè gbà ràn-án lọ́wọ́. Bákan náà, ọ̀dọ́kùnrin kan ní ìlú Kánò, ti wọn fi sẹkẹ́sẹkẹ̀ so mọ́lẹ̀ ní ibùdó ìfiniwọ̀ kan, ní esinsin ń kùn, tí oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine nínú tó ń mu fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ osù pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, sì ti sọ di alárùn ọpọlọ.

Ìbànújẹ́, ìpòrúru ọkàn àti ìgbìnyànjú láti lókun wà lára àwọn ohun tó ń fa àwọn ọmọ Nàíjíríà lọ sí ìdí mímu oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine. Àwọn olórin ń yòǹbó bó se leè mú kí èèyàn wà pa.

Àwọn òǹtàjà náà ń pin kiri àwọn ilé ijó lálẹ́, tó fi mọ́ ojú pópó. Àwọn ọ̀dọ́ ń lu pọ̀ mọ́ ohun mímu ẹlẹ́rìndòdò, tàbí kí wọn da ìgò rẹ̀ kọnu tààràtà ní "agbo ìpéjọpọ̀ oògùn ikọ́ olómi."

Kò sí òfin kankan tó lòdì sí síse tàbí mímu oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine sùgbọ́n òfin tako títa òògùn náà fáwọn èèyàn láìsí àsẹ látọ̀dọ̀ dókítà tàbí káwọn tí kò ní ìwé àsẹ máa tàá.

"Kódà, bí èèyàn bá fẹ́ ra páálí ẹgbẹ̀rún kan, a kò ní fún wọn ní rìsítì". Ọ̀gbẹ́ni Hazzan sọ fún wa, pẹ̀lú àlàyé bó se máa ń sá fáwọn alásẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFídíò òògùn ikọ́ Codeine: Àpọ̀jù rẹ̀ ń ya ọ̀dọ́ ní wèrè

Gẹ́gẹ́ bíi àwọ̀ǹ òògùn olóró yòkúù, èròjà codeine jẹ́ mọ̀lẹ́bí kan náà pẹ̀lú heroine. Ó wúlò láti wo ara ríro sùgbọ́n ó leè jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ládùnjù. Ó máa ń jẹ́ kòsee-mámu, táa bá sì muú jù, ó leè ní ipa tí kò dára lórí ọpọlọ àti ara.

Òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine - ibití wàhálà rẹ̀ dé

  • Bí Codeine je oògùn ara ríro náà ni wọn ń lòó gẹ́gẹ́ bí i egbògi olóró ní èyí tí àpọ̀jù rẹ lè fa àrùn ọpọlọ àti ki ẹ̀yà ara kọ iṣẹ́.
  • Ọpọ̀ ìgbà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń da oògùn ikọ́ olómi Codeine papọ̀ mọ́ ẹlẹ́rìndòdò wọn.
  • Wón ń kó Codeine wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè ni ṣùgbọ́n àwọn iléeṣẹ́ tó ń se òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine síta lé ní ogún ni Nàìjíríà,
  • Àjọ tó ń gbógun ti àṣìlò oògùn olóró ní Nàìjíríà (NDLEA) ń gbógun ti àṣìlò rẹ̀.
  • Láìpẹ́ ni NDLEA gbẹ́sẹ̀lé ìgò oògùn ikọ́ olómi Codeine ẹgbẹ̀rún mérìnlélógún nínu ọkọ̀ agbégi kan ní ìpílẹ́ Katsina.
  • Wàhálà lílo oògùn ikọ́ olómi Codeine gẹ́gẹ́ bíi oògùn olóró ti di káríayé nilẹ̀ Afrika báyìí pẹ̀lú ìròyìn láti Kenya, Chad, Ghana ati Niger.
  • L'ọdún 2016 ni India fòfin de kí iléeṣẹ́ oríṣíi máa po òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine síta látàri pe àwón kan ti ń ṣìí lò.

Àṣìlò òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine nínú máa ń fa ki kíndìrín bàjẹ́, gìri, ọpọlọ dídàrú àti orí yíyí.

Àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ tó ń mójútó àyípadà àwọn ti wón ń mu oògùn ikọ́ olómi Codeine bíi egbògi olóró máa ń so wọn mọ́lẹ̀ ni.

Ogbeni Usaini ṣalaye fún mi lori ọkan lára wón ti mo duro tì pé: kò lè sùn si orí ibùsùn nítori pe O ti ba ibùsùn rl jẹ́, o ti fọ́ fèrèsé láti fi ṣe ọṣẹ́ fún ara rẹ̀" .

'ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí ló máa ń sunkún ti wọn bá wa wo awọn ọmọ wọn níbí'.

Àkọlé àwòrán Emzor ní òun ti ń se ìwádìí Chukwunonye Madubuike (ọwọ́ ọ̀tún)

Àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ apo-òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine síta mọ̀ nípa ewu tó rọ̀ mọ́ àṣìlò òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine.

Ogbeni Chukwunonye Madubuike, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ẹ̀ka ọjà tita ni Iléesẹ́ Emzor pharmaceuticals náà ló ta ọgọ́ta ìgò òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine nínú nílé ìtura kan nilu Eko.

O ní: 'ti ó ba ti di bárakú fún ẹnìkan, yóò má a wa owó kiri ni. ...ṣe srs mi ń ye ẹ?... mo ms pé ti mo ba ni èròjà yìí tótó milionu páálí kan lọ́wọ́, mo mọ̀ pé màá tàá tán lọ́sẹ̀ kan ṣoṣo."

Àkọlé àwòrán Àwọn òsìsẹ́ tó ń gbógun ti òògùn olóró ní Nàíjíríà fi idà yìí han Ruona Meyer, èyítí wọn gbà lọ́wọ́ àwọn amu òògun olóró

Iléesẹ́ Emzor pharmaceuticals sọ fún wa pé, òun ti bẹ́rẹ́ ìwádìí lórí Ogbeni Madubuike ati ọ̀nà ti wọn fi ń pín òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine síta.

Opọ̀ ìgbà ni NDLEA máa ń jáde lọ kó àwọn ti wón ń mu oògùn ikọ́ olómi Codeine bíi egbògi olóró pàápàá ní ìpínlẹ̀ Kano.

Àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ NDLEA fi tóònù meji oògùn ikọ́ olómi Codeine ti Bioraj Biolin pharmaceuticals ti wọn gbẹ́sẹ̀lé hàn wá pẹ̀lú ohun eelò ìjà olóró bii ọ̀bẹ, àdá, àkọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àkọlé àwòrán Àwọn ìgò oògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine ń polówó èròjà codeine tó wà nínú wọn

Mímu òògùn ikọ́ olómi kò kan ipò, ìran tàbí ẹ̀ya

Hamza Umar ti NDLEA Kano ní, mímu òògùn ikọ́ olómi kò ní nkàn ṣe pẹ̀lú boya olówó. olòṣì, ọ̀mọ̀we tàbi púrúǹtù ni kódà, àwọn ọmọdegan ń lòó.

A ri ómó ódun merindinlogun kan to fi hijab bo ojú rẹ̀ lára àwọn to wa niyàrá tí kò ni fèrèsé.

Ara rẹ̀ ṣi ń gbọ̀n lẹ́yìn oṣù méjì.

O ni ọ̀rẹ́kùnrin òun lo ń fún òun mu leyin ile iwe.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí