Twitter Password; E se àyípadà láti dáàbò bo ojú òpó yín

Aworan idanimọ Twitter Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eniyan 330 Millionu lo n lo oju opo ikansiraẹni Twitter

Ile isẹ ikansiraẹni Twitter ti kilọ fun awọn ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún milliọnu (330 million) eniyan to n lo oju opo naa lati yi amin iwọle ‘password’ wọn pada lati da abo bo awọn iroyin to wa loju opo wọn.

Twitter ni igbesẹ naa pọn dandan lẹyin ti iwadii fi han wipe awọn kan ni ile-isẹ naa gba ọna ẹburu lati ji password awọn eniyan to n lo oju opo naa.

Osisẹ ile isẹ sọ fun iwe iroyin Reuters wipe Twittter ri asemase naa ni ọsẹ meji sẹhin ti wọn si kesi awọn to mọ̀ nipa rẹ lati se atunse to peye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alasẹ Agba fun ile isẹ naa, Jack Dorsey ni oju opo Twitter rẹ sọ wi pe, awọn ti se atunsẹ to peye lori iwadii wọn, ati wi pe ‘password’ awọn eniyan ti ọrọ naa kan ko po.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eniyan 330 Millionu lo n lo oju opo ikansiraẹni Twitter

Sugbọn, o kesi awọn eniyan lati se ayipada password wọn.