Wọ́n yìn'bọn lu mínísítà abẹ́lé ni Pakistan

Ahsan Iqbal nigha iforowanilenu wo pelu oniroyin ni Islamabad, Pakistan, ni ọjọ kejila oṣu kẹfa, ọdun 2017 Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Iqbal jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú Pakistan Muslim League (Nawaz) tí ó ń ṣ'elu ni orílẹ́èdè náà.

Agbébọn kan ni a gbọ pe o ti yan'bọn lu Minisista fun ọrọ abẹle ni Pakistan Ahsan Iqbal nigba ti o wa ni agbegbe rẹ ni ilu Narowal.

Iroyin fi to wa l'eti wipe Iqbal ṣẹṣẹ kuro ni ibi ipejọ kan ni Punjab ni agbebọn naa ṣe akọlu sii ti o si yin n'ibọn ni apa. Oju ẹsẹ ni wọn gbe lọ ile iwosan nibi ti o ti n gba itọju bayi lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ abẹ fun.

Awọn ọlọpaa ni ẹsẹkẹsẹ ni awọn mu agbebọn naa ti o jẹ ẹni ogun ọdun le diẹ lati fi ọrọ waa lẹnu wo.

Iqbal ni o jẹ ọkan gbòógi ninu Pakistan Muslim League (Nawaz) ti o n ṣ'elu ni orilẹede naa.

Orilẹede Pakistan, Shahid Khaqan Abbasi ti bẹnu atẹ lu akọlu naa.