Ẹkùn Gúúsù Òndó nínú òkùnkùn f'ọdún Mẹ́wàá

Àwòrán àwọn afehonu han Image copyright Seun Sogbon
Àkọlé àwòrán Wọn bù ẹnu àte lu ìjọba fún irú ipò tí Ìlú náà wà.

Àìsí iná mọnamọna ti ba ètò ọ̀rọ̀ aje wa jẹ́ pátápátá

Àwọn ènìyàn abúlé Ìgbọ́kọ̀dá níjọba ìbílẹ̀ Ìlájẹ nipinle Òndó ti ké gbàjarè pé ó ti pé ọdún mẹ́wàá gbáko tí àwọn tí ni iná ọba kẹ́yìn.Wọn bù ẹnu àte lu ìjọba fún irú ipò tí Ìlú náà wà, àwọn ará ìlú ọhun tún sọ bákan náà pé ètò ìdìbò kankan kò ní wáyé láì ṣe pé iná mọnamọna wọ ìlú wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣùgbọ́n, ìwádìí BBC Yorùbá fi hàn pé ìlú ìgbọ́kọ̀dá nìkan kọ́ ló wà nínú ìṣòro yìí, bí kò ṣe ìjọba ìbílẹ̀ márùn-ún nínú mẹ́fà tó wà ní ẹkùn Gúúsù ìpínlẹ̀ Òndó

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸkùn Gúúsù Òndó nínú òkùnkùn fọ́'dún Mẹ́wàá

Ọ̀kan lára àwọn ará ìlú tọ́rọ̀ náà kàn bá ikọ̀ BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, nínú àlàyé rẹ̀, Ó sọ pé, ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtì pupa, Ìlàjẹ, Òdìgbó, Ẹsẹ̀-odò, Òde ìrèlè ló wà

nínú òkùnkùn birimu-birimu láti oṣù kẹta ọdún 2013

Bákan náà, BBC Yorùbá, bá olùránlọ́wọ́ pàtàkí sí Gómìnà Ipínlẹ̀ Òndó lóri ètò amúlùdùn, onímọ̀ ẹ̀rọ Tunji Aríyọ̀mọ́ sọrọ.

O sàlàyé pé, o ti tó odun mẹrìndínlogun fáwọn ìlú míràn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸkùn Gúúsù Òndó nínú òkùnkùn fọ́'dún Mẹ́wàá

O ní ìjọba to ń bẹ lóde ní ìpínlẹ̀ Ondo ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti fòpin sí ìṣòro ọhun.

A ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti fọwọsọpọ pẹlu awọn miran lori ọrọ owó lati tun awọn nkan tó bàjẹ́ ṣe.