Buhari sèpàdé atilẹkun mọri se pẹ̀lú àwọn aṣáájú ile aṣòfin

Aworan Buhari ati áwọn aṣáájú ilé Image copyright TWITTER/NIGERIAN PRESIDENCY
Àkọlé àwòrán Lóore k'ore láwọn aṣáájú ilé àti Ààrẹ Buhari má n ṣe ìpàdé

Ààrẹ Buhari àti àwọn aṣáájú ilé aṣòfin Nàìjíríà, aṣòfin Bukola Saraki àti Yakubu Dogara ti ní ìpàdé tilẹkun mọri ṣe labuja.

ìpàdé náà tó wáyé ní kété ti Ààrẹ dari láti Daura lọjo aje da lórí àwọn ọrọ tó ní ṣe pẹlu ètò ilu.

Pàtàkì nínú ọrọ tí wọn sọ ni bi wọn yóò ṣe buwọ́lù aba ìṣúná ọdún 2018.

Image copyright Twitter/Presidency Nigeria
Àkọlé àwòrán Ọrọ aba ìṣúná ọdún 2018 tí n kò òpó lominu ní Nàìjíríà

Láti oṣù kẹwa ọdún 2017 ni Ààrẹ ti fi aba náà ṣòwò sí ilé.

Awuyewuye bẹ lẹ̀ lórí aba náà nígbà tí àwọn aṣòfin sọ pé awọn ileese ìjọba kọ̀ lati yọju ṣe àlàyé bi wọn ṣe fẹ ná ọwọ ìṣúná náà.

Bákan náà ni wọn jíròrò lórí ọrọ ọgá ọlọ́pàá ti Senato Bukola Saraki ni o kọ láti yọjú sí ilé lẹ̀ẹ̀meji.

O tun mẹnu bá ọrọ Senato Dino Melaye ti o ni o kú diẹ kaato bi ọlọ́pàá ṣe mú ọrọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: