Bàbá ọmọ tí Mammadou Gassama dóòlà ẹ̀mí rẹ̀ rẹ́wọ̀n he ní France

Mamoudou Gassama pade Emmanuel Macron

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Aare France Emmanuel Macron gba Gassama lalejo lojo Aje.

Baba ọmọde kan ti Mammadou Gassama, ọmọ orilẹede Mali doola ẹmi rẹ nigba to gun ile alaja mẹrin lati gbe ọmọ na sọ kalẹ, lọ ẹwọn bayii.

Ẹwọn oṣu ẹta ni adajọ fun baba ọmọde naa fun ẹsun pe o kuna ni iṣẹ rẹ gẹgẹ bii obi. Adajọ ni ki arakunrin naa lọ gba ẹkọ ninu bi obi rere ṣe maa n ṣe.

Iroyin ni baba naa fi ọmọ rẹ silẹ lọ ra ọja ni, ṣugbọn ko tete pada sile nitori pe o n ta tẹtẹ. Ọrọ naa lo sọ Gassama di olokiki jakejado agbaye bi fidio kan ṣe jade nibi to ti n fo ile alaja mẹrin lati lọ doola ẹmi ọmọ naa tó fẹ́ ré jábọ́.

Iwà akin tí Mamoudou Gassama hu yìí tí ṣokunfa ìpàdé pẹlú Ààrẹ France, Emmanuel Macron, ni ilé ìjọba Elysee Palace, to sì fún un ní ẹ̀tọ́ àti gbe ilu.

Níbi ìpàdé náà ni Ààrẹ Macron ti kàn saara sí Mammadou Gassama fún iwà akin tó hù.

Bákan náà lo fi àmì ẹ̀yẹ da a lọla to sì tún fún un ní iṣẹ gẹgẹ bí panapana.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Mammaadou ṣe afihan iwe ami eye ti Aare Macron fi da lola

L'ọdun to kọ́ja ni Gassama gbà orí omi kọjá dé sí orílè-èdè France.

Ọnà tó gbà ṣe oríire bẹrẹ nígbà tí o n lọ jẹjẹ ládugbó kan níbi tó ti ri awọn èèyàn tó pejọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí: