June 12: Àwọn òwe tí MKO Abiọla ń pa nígbà ayé rẹ

MKO Abiola

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gba ǹkan tí ọlọ́rún ṣe fún ẹ kí o sì lòó dáradára"

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló tí ń se sàdá n kátà fún ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari, fún ìgbésè rẹ̀ lóri sísọ June 12 di àyájọ́ ọjọ́ ìṣèjọba àwa arawa lẹyìn ọdún márùndínlọ́gbọ̀n àti fífi oyè GCFR dáa lọ́lá ní ipò òkú.

Fún ìdí èyí, ó ṣe pàtàkì láti rántí àwọn ọ̀rọ̀ àyolò tàbí òwe méjìla ti Moshood Kashimawo Ọlawale Abiọla ti pa, eyi tàwọn ọmọ Nàìjíríà kò le gbàgbé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ jẹ́ ká yẹ àwọn àyọ́lò ọ̀rọ̀ náà wò:

 • Gba ǹkan tí ọlọ́rún ṣe fún ẹ, kí o sì lòó dáradára
 • Ẹní to bá lọ yáwó, yóò rí ìbànújẹ́
 • O kò leè pa ọmọ tuntun nítorí pé ìyá agbẹ̀bí jẹ́ ènìyàn búburú
 • Kò sí eni tó le fún ni lágbara, tìrẹ ní, Gbàá!
 • Láti òni lọ, ẹ fi han gbogbo ayé pe, gbogbo ẹni tó bá pe àwọn ọmọ orílẹ-èdè Nàìjíríà ní aṣiwèrè ń tan ara rẹ ní, yóò sì káwọ́ pọnyìn rojọ́ niwaju yin.
 • Ẹyin ènìyàn Nàìjíríà, àsìkò wa nìyí. Ẹ̀yin ni ibi ìpamọ agbára ilẹ̀ yìí.
 • Kò sí ìdójú tí ń kò tíì faradà, kò sí ìrẹ̀wẹ̀sì tí wọn ko tíì dẹ sí ọ̀nà mi, kò sí àrékérekè tí wọn kò pínnu fún mi nínú ìlàkàkà mi láti lo ipa àlààfíà fi ri dájú pé mo gba asẹ tí ẹ fún mi.
 • A kìí fárí lẹ́yìn olórí
 • Àìtó ìwé àti irinṣẹ ikẹkọọ tí sọ àwọn ilé ẹkọ́ wa di ahoro aṣáàlẹ̀ fáwọn alaimọkan
 • Ọkàn wa ń bàjẹ́ láti rí àwọn èèyàn tí kó se àfihàn nkan-kan, tàbí tí kò ní àseyọrí tara wọn, bóyá nínú dídá iléesẹ́ àdáni sílẹ̀ ni tàbí síse àseyọrí kankan dàbí alárà nínú ohunkohun, tí wọn wá fi irú wọn sí àkóso ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè wa, láti ọwọ́ àwọn alásẹ tí wọn kò jíyìn isẹ́ ìríjú wọn fún ẹnikẹ́ni.
 • Àwọn ọ̀dọ́ wa, ní pàtàkì jùlọ kò le rí ìrètí, tí ọ̀pọ̀ sí ń ronú àti sá kúrò lórílẹ̀-èdè yìí láti dara pọ̀ mọ́ ọ̀dá ọpọlọ tó ń bá wa fínra.
 • Bákàn náà ni àì sòòtọ́ọ́ nínú owó sísan, ti sọ àwọn ilé ìwòsàn àti ibùdó igoogun di ibi ti kò sí òògùn pàtàkì mọ, tí wọn sì tí di ilé igbòkú sí