Italy da ọ̀pọ̀ Aláboyún àt'àwọn arìnrìnàjò obinrin padà níbodè

Aworan awọn arìnrìnàjò Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mínísítà Italy fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Matteo Salvini ni kò sí ààyè fún ìrìnàjò ti kò tọ́ ní Italy mọ

Nàìjírìà ní orílẹ̀-èdè kẹ̀ta tó pòjù lọ tó ń kọjá lọ sórílẹ̀-èdè Libya lọna àìtọ́ lẹ́yìn Syria àti Afgan.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ní ìjọba ti dá pádà wále láìpẹ́ yíì nítorí iṣekú-pani to ń waye níbẹ̀ láti ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè Libya.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn ènìyàn yìí máa ń rápálá wọ Libya lójúnà àti kọja lọ sí orílẹ̀-èdè Italy.

Àkọlé àwòrán Agbegbè ibi ti àwọn arinrinajo naa wa súnmọ Malta ju Italy lọ

Ní báyìí èsúrú ọ̀rọ̀ náà ti pàdídà, ó ń lé ajá, bí òrílẹ̀-èdè Italy ṣe fárígá pé àwọn àrinrìnàjò lọ́nà àìtọ́ tí àjọ ẹléyin jú àànú orílẹ̀-èdè Germany kan tí wọn ń pè ni SOS Méditerranée dóòlà kò ni wọlé sí Italy.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸtàn ni àwọn ọ̀rẹ́ fi ń tan èèyàn lọ si Libya pé iṣẹ́ gidi wà níbẹ̀

Ènìyàn mọkàndinlọgbọnlélẹgbẹta ní àwọn àjọ náà dóòlà nínú odò Meditereanian lágbàgbè tó súnmọ́ Libya.

Kini ìdí ti Italy fi Fariga:

Mínísítà Italy fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Matteo Salvini, ni orílẹ̀-èdè Italy sọ pe, apá ibi tí wọ́n ti kó àwọn arinrìnàjò ọ̀hún súnmọ́ orílẹ̀-èdè Malta ju Italy lọ.

Yàtọ̀ sí èyí, Italy ti pinnu pe òhún yóò fi òpin sí ìrìnàjò lọ́nà àìtọ́ wọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ti sọ ọ̀nà ibẹ̀ di ibi tí wọn ń gbà wọ Yuroopu.