Iléesẹ́ ọlọ́pàá: Ihò tí wọ́n gbẹ́ fún wáyà, ni eku gbà wọlé

Àwọn eku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ó ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́nu pé eku jẹ owó nínú ẹ̀rọ tó ń pọ owó

Awọn amoju-ẹro ti wọn n tun ẹrọ apọwo to bajẹ ṣe ni ilu Assam l'orilẹede India, ti ṣ'akiyesi pe, awọn eku ti jẹ owo ti wọn ko si inu ẹrọ naa.

Owo ti o to $17,600 ni wọn ri pe eku ti jẹ, nigbati wọn ṣii ẹrọ naa.

Awọn ọlọpaa sọ pe, o ṣeeṣe ki awọn eku naa raye wọle loju iho ti waya gba kọja lọ sinu ẹrọ owo ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọlọpaa kan ti orukọ ré n jẹ Prakash Sonowal fidi ré mulẹ pe, ẹrọ naa ko ti i ṣiṣẹ fun ọjọ mejila.

Aworan ẹ́rọ̀ to n pọ owo naa tiẹ se afihan eku kan to ku sinu ẹrọ naa, ti àwọn owo beba to wa ninu ẹrọ naa si ti ya wẹlẹ́-wẹlẹ.

Awọn onimọ-ẹrọ to gbe ẹrọ apọwo naa ri awọn owo beba ẹ́gbẹrun meji alapapọ ati ẹẹdẹgbẹta alapapọ ti wọn jẹ owo Rupee, tawọn eku ọhun ti bajẹ.

Sugbọn wọn tiraka lati doola owo Rupee to to milliọ̀nu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin to wa ninu ẹrọ apọwo naa, ko to pẹju.